ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/06 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 4/06 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nígbà àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 24, 2006. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ March 6 sí April 24, 2006. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti sọ ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Nígbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ dánu dúró díẹ̀ ká tó bọ́ sí orí kókó mìíràn, ṣùgbọ́n kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀? [be-YR ojú ìwé 98 ìpínrọ̀ 2 sí 3]

2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa dánu dúró bá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn? [be-YR ojú ìwé 99 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 100 ìpínrọ̀ 4]

3. Kí nìdí tí títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ fi ṣe pàtàkì nígbà téèyàn bá ń sọ àsọyé, báwo la sì ṣe lè mọ ọ̀nà tó dáa láti gbà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀? [be-YR ojú ìwé 101 sí 102 ìpínrọ̀ 1 sí 5, àpótí]

4. Nígbà tá a bá ń kàwé fún àwùjọ, báwo la ṣe lè rí i pé a tẹnu mọ́ àwọn kókó tó wà nínú gbólóhùn kọ̀ọ̀kan tá à ń kà? [be-YR ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 1 sí 6]

5. Kí nìdí tó fi bójú mu pé kí ẹni tó ń kọ́ni lo ohùn bó ṣe yẹ, báwo la sì ṣe lè mọ bó ṣe yẹ ká gbóhùn sókè tó? [be-YR ojú ìwé 107 sí 108]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Àwọn àǹfààní wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tòde òní ń rí látinú ìwé Ẹ́sítérì? [w86-E 3/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 18]

7. Nígbà tí Sólómọ́nì sọ pé “asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù,” kí ló ń ṣàpèjúwe? (Oníw. 2:11) [w04-YR 10/15 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 3 sí 4]

8. Báwo la ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? (Máàkù 12:30) [w04-YR 3/1 ojú ìwé 19 sí 21]

9. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín kéèyàn nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí àti kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì? [w04-YR 10/15 ojú ìwé 5 sí 7]

10. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fetí sílẹ̀ láìjẹ́ kí ọkàn wa pínyà nígbà tá a bá wà láwọn àpéjọ? [be-YR ojú ìwé 15 sí 16]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Kí nìdí tí wọ́n fi bo Hámánì lójú? (Ẹ́sítérì 7:8)

12. Ẹ̀dá ẹ̀mí wo ló mú kí Élífásì ronú lọ́nà tó gbà ronú yẹn? (Jóòbù 4:15, 16) [w05-YR 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 2]

13. Ṣé ọ̀rọ̀ Jóòbù tó wà lákọọ́lẹ̀ ní Jóòbù 7:9, 10 àti Jóòbù 10:21 fi hàn pé kò gba àjíǹde gbọ́?

14. Kí ló ṣeé ṣe kí Jóòbù ní lọ́kàn pẹ̀lú gbólóhùn tó sọ pé “bí awọ eyín mi ni mo sì fi yèbọ́”? (Jóòbù 19:20)

15. Kí ni Jóòbù ní lọ́kàn ní sísọ tó sọ pé, “èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi,” kí la sì lè rí kọ́ látinú èyí? (Jóòbù 27:5)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́