Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù April àti May: Ká lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tá a bá padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn ìpàdé mìíràn tí ìjọ ṣètò àmọ́ tí wọn kò dara pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ìjọ, ká fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa fi ìwé yẹn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. June: Ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn kan bá sì sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.
◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé (S-205-YR) àti Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ (S-205b-YR) tí ó pọ̀ tó wà lọ́wọ́. Ẹ lè béèrè fún àwọn fọ́ọ̀mù yìí nípa lílo fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, Literature Request Form (S-14). Kẹ́ ẹ rí i pé èyí tí ìjọ ní lọ́wọ́ yóò tó lò fún ọdún kan, ó kéré tán. Ẹ máa ṣàyẹ̀wò gbogbo fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé láti rí i dájú pé ìsọfúnni inú wọn pé pérépéré. Kẹ́ ẹ tó wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí ìjọ.
◼ Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí ní àkọsílẹ̀ àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù tí gbogbo alága àwọn alábòójútó àti akọ̀wé ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́. Bí ìyípadà bá wà nígbàkigbà, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kọ àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù tí wọ́n ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ sínú fọ́ọ̀mù Presiding Overseer/Secretary Change of Address (S-29) [Ìyípadà Àdírẹ́sì Alága Àwọn Alábòójútó àti Akọ̀wé], kí wọ́n buwọ́ lù ú, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ́gán. Èyí kan ìyípadà tó bá wà nínú nọ́ńbà tẹlifóònù wọn.
◼ Gbàrà tí ìjọ bá ti gba Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tuntun ni kẹ́ ẹ ti kó wọn sóde káwọn ará lè rí i gbà. Ìyẹn á jẹ́ káwọn akéde tètè ka àwọn àpilẹ̀kọ inú àwọn ìwé ìròyìn náà kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lò wọ́n lóde ẹ̀rí. Gbàrà tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa náà bá ti tẹ̀ yín lọ́wọ́ ni kẹ́ ẹ ti pín wọn fáwọn ará. Ẹ tiẹ̀ lè pín wọn fáwọn akéde ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ pàápàá.
◼ Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí kì í fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alága àwọn alábòójútó ṣètò ká máa ṣèfilọ̀ lóṣooṣù ká tó fi fọ́ọ̀mù tí a fi ń béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ nílò fún oṣù kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ gba ìwé tirẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tó ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tá a máa ń kọ̀wé béèrè fún lákànṣe.
◼ Ní May 27, 2006, kò ní sí ààyè fún wa láti gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kẹ́ ẹ má ṣe wá gba ìwé lọ́jọ́ náà.