ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/06 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 8/06 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nígbà àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 28, 2006. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ July 3 sí August 28, 2006. [Àkíyèsí: Níbi tá ò bá ti sọ ibi tá a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Báwo ni wíwo ojú ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti di olùkọ́ tó jáfáfá? (Mát. 19:25, 26; Ìṣe 14:9, 10) [be-YR ojú ìwé 124 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 3]

2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá a, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá? [be-YR ojú ìwé 128 ìpínrọ̀ 1 sí 5, àpótí]

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wà ní mímọ́ tónítóní ká sì máa túnra ṣe? [be-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 1 sí 3]

4. Ọ̀nà wo ni “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú” lè gbà ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú aṣọ àti ìmúra tó yẹ? (1 Tím. 2:9) [be-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 132 ìpínrọ̀ 1]

5. Ìlànà Bíbélì wo ló yẹ ká máa tẹ̀ lé láti lè rí i pé ìrísí wa ò dà bíi ti ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ayé? [be-YR ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 2 sí 3]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Àǹfààní tó dáa jù lọ wo la lè rí látinú ìwé kíkà? [be-YR ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 3]

7. Kí la fi ń mọ ọlọ́gbọ́n yàtọ̀ sí òmùgọ̀? (Òwe 14:2) [w04-YR 11/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 5]

8. Kí nìdí tí ‘ìmọ̀ fi jẹ́ ohun rírọrùn sí olóye’? (Òwe 14:6) [w04-YR 11/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 4 sí 5]

9. Kí ni ìkẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3]

10. Àwọn ọ̀nà wo ni àṣàrò tá a bá ṣe lórí àwọn ohun tí Jèhófà dá lè gbà ṣe wá láǹfààní? [w04-YR 11/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 4]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Láyé ọjọ́un, báwo ni Jèhófà ṣe “sọ àsọjáde” tó wá yọrí sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá “àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere,” báwo lèyí sì ṣe ń ṣẹlẹ̀ lóde òní? (Sm. 68:11)

12. Kí ló fẹ́rẹ̀ẹ́ mú kí Ásáfù ṣíwọ́ nínú ṣíṣe ohun tó tọ́, báwo sì ló ṣe tún ìrònú ara rẹ̀ ṣe bọ̀ sípò? (Sm. 73:2, 3, 17)

13. Kí nìdí tí wọ́n fi ń pe mánà tí Ọlọ́run pèsè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní “ọkà ọ̀run” àti “oúnjẹ àwọn alágbára”? (Sm. 78:24, 25)

14. Ibo ni “ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,” báwo la sì ṣe lè “gbé” ibẹ̀? (Sm. 91:1, 2)

15. Ọ̀nà wo ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin Jèhófà gbà ṣeyebíye lójú rẹ̀? (Sm. 116:15)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́