Lo Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa Lọ́nà Tó Bọ́gbọ́n Mu
1 A bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́nà tó wà létòlétò látorí Ilé Ìṣọ́, July 1, 1879. Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] lára Ilé Ìṣọ́ yìí la pín káàkiri nígbà yẹn. Látìgbà yẹn wá, a ti tẹ onírúurú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, a sì ti pín wọn kiri lọ́pọ̀ jaburata.
2 Orí Ọrẹ Àtọkànwá Ló Dá Lé: Ní December 1999, a ṣàlàyé pé a óò máa tẹ ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ fáwọn akéde àti fún gbogbo àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí wọn àti pé ọrẹ tó bá tọkàn ẹnì náà wá ló lè fi ṣètìlẹ́yìn, ìyẹn ni pé, a ò ní máa béèrè fún iye owó kan ní pàtó tàbí ká dọ́gbọ́n dá iye kan lé e kí wọ́n tó lè rí ìwé wa gbà. Nígbà tá a bá fún àwọn èèyàn níwèé, a ó gba iye tí wọ́n bá fínnúfíndọ̀ fún wa láti fi ṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kíkéde ìhìn rere tá à ń ṣe kárí ayé. Kò síyè méjì pé ọwọ́ Jèhófà wà nínú ìṣètò yìí.—Fi wé Mátíù 6:33.
3 Bá A Ó Ṣe Máa Ṣe É Lóde Ẹ̀rí: Kọ́rọ̀ wa bàa lè máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, a ó máa bá a nìṣó láti lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a ti múra ẹ̀ sílẹ̀ dáadáa. Bẹ́nì kan ò bá fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ sọ̀rọ̀ tá à ń bá òun sọ, kò yẹ ká fún un ní ìwé. Kò yẹ ká máa fi ìwé wa ṣòfò nípa fífún àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Àmọ́, bá a bá rẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, tẹ́ni náà sì gbà láti ka ìwé náà, a lè fún un. A ní láti lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu.
4 Lẹ́yìn tó o bá ti fi ìwé náà han ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, tónítọ̀hún sì fi hàn lójú ẹsẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ sí i tó sì gbà á, o lè sọ pé: “Ìwé yìí á ṣe ọ́ láǹfààní o. Ọ̀pọ̀ ló fẹ́ mọ ibi tá a ti ń rówó tẹ àwọn ìwé tá a máa ń pín káàkiri yìí. Ọ̀pọ̀ tó ti gbà lára àwọn ìtẹ̀jáde wa ló ti fi ìmọrírì hàn fáwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n máa ń rí kọ́ látinú ẹ̀ tí wọ́n sì fi tinútinú ṣètìlẹ́yìn níwọ̀nba kí iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé yìí lè máa tẹ̀ síwájú. Bá a bá rẹ́ni tó ṣe irú ìtìlẹ́yìn yìí, tayọ̀tayọ̀ lá fi máa ń gbà á.”
5 Ṣé Ẹni Yẹn Nífẹ̀ẹ́ sí I Lóòótọ́? Ó dájú pé kì í ṣe pé a fẹ́ máa pín ìwé wa yàlà-yòlò. A fẹ́ kí àwọn ìwé wọ̀nyí ṣe ohun tá a tìtorí ẹ̀ tẹ̀ wọ́n, ìyẹn ni pé, kí wọ́n ran àwọn tí òtítọ́ ń wù lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà fẹ́ ṣe. Bí ẹní fi ṣòfò ló máa jẹ́ bá a bá ń fún àwọn èèyàn tí ò mọrírì ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ìwé wa. (Héb. 12:16) Kí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń pín kiri tó lè méso jáde, o ní láti dá ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa mọ̀. Báwo lẹnì kan ṣe lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa? Àmì kan tó dáa ni pé ẹni náà á fàyè sílẹ̀ láti bá ẹ fọ̀rọ̀ wérọ̀. Láti jẹ́ kó o mọ̀ pé ọkàn rẹ̀ wà níbi ìjíròrò náà, á fetí sílẹ̀ nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀, á máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó o bá bi í, á sì máa sọ èrò rẹ̀. Bó bá bá ẹ sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bíi pe ẹ jọ jẹ́ aládùúgbò, a jẹ́ pé èèyàn dáadáa ni. Bó bá ń fọkàn bá Bíbélì tó ò ń kà lọ a jẹ́ pé ó fọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa dáa kó o béèrè bí wọ́n bá máa ka ìwé tó o fún wọn. Bákan náà, o lè jẹ́ kó mọ̀ pé wàá fẹ́ padà wá kẹ́ ẹ lè tẹ̀ síwájú nínú ìjíròrò náà. Bó bá gbà bẹ́ẹ̀, ìyẹn tún jẹ́ ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí i. Bó o bá kíyè sí irú àwọn àmì ojúlówó ìfẹ́ sí òtítọ́ tá a mẹ́nu bà yìí lára ẹnì kan, ó ṣeé ṣe kẹ́ni náà lo ìwé tó o bá fún un dáadáa.
6 Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tá A Fẹ́ Lò Fúnra Wa: Ní gbogbo ìgbà tá a bá gba àwọn ìtẹ̀jáde tá a fẹ́ lò la gbọ́dọ̀ máa rántí pé ojúṣe wa ni láti ṣètìlẹ́yìn. A lè ṣètìlẹ́yìn náà nígbà tá a bá gbàwé tàbí ká ṣe é nígbà míì. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìtẹ̀jáde tó wà lọ́wọ́ wa dọ̀tí tàbí kó bà jẹ́. Ó máa túmọ̀ sí pé a ò lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa yìí lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu bá a bá jẹ́ káwọn ọmọdé sọ àwọn èèlò ṣíṣeyebíye yìí dohun ìṣeré.
7 Bí ìparun Bábílónì Ńlá ṣe ń sún mọ́lé sí i ni pákáǹleke tó ń bá gbogbo ìsìn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Olórí àníyàn wa ni pé kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì yìí, máa tẹ̀ síwájú láìsí ìdíwọ́, kí ọ̀pọ̀ èèyàn bàa lè rí ìgbàlà.—Mát. 24:14; Róòmù 10:13, 14.