Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 25, 2006. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ November 6 sí December 25, 2006. [Àkíyèsí: Níbi tá ò bá ti sọ ibi tá a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá fẹ́ yan ọ̀rọ̀ tó tọ́ láti fi nasẹ̀ Ìwé Mímọ́? [be-YR ojú ìwé 148 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 149 ìpínrọ̀ 1]
2. Kí ni díẹ̀ lára onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn? [be-YR ojú ìwé 151 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 152 ìpínrọ̀ 3]
3. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iṣẹ́ ńlá ni kíkọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ló yẹ ká ṣe bá a bá máa ‘fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́’? (2 Tím. 2:15) [be-YR ojú ìwé 153 ìpínrọ̀ 1 sí 3 àti àpótí; ojú ìwé 154 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
4. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà mú kí ìwúlò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kà ṣe kedere? [be-YR ojú ìwé 154 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 155 ìpínrọ̀ 2]
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí àwùjọ rí bá a ṣe lè fi ọ̀rọ̀ náà sílò, báwo la sì ṣe lè ṣe é? [be-YR ojú ìwé 157 ìpínrọ̀ 1 sí 5 àti àpótí]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Lọ́nà wo ni ‘kò fi sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn’? (Orin Sól. 1:9) [w87-YR 9/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 4 àti 5]
7. Báwo ni àwọn iṣẹ́ olódodo ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run? (Oníw. 9:1) [w87-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 9 àti 10]
8. Kí ni ìtumọ̀ fífi tí omidan Ṣúlámáítì fi “àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù” sábẹ́ ìbúra pé ‘kí wọ́n má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú òun, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè’? (Orin Sól. 2:7; 3:5) [w87-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 12]
9. Kí ló mú kí òkùnkùn túbọ̀ bo ayé lónìí? [w01-YR 3/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 8 àti 9]
10. Kí ló lè ran olùbánisọ̀rọ̀ kan lọ́wọ́ láti má ṣe ní àkọsílẹ̀ tó gùn jù? [be-YR ojú ìwé 42 ìpínrọ̀ 2]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Báwo ló ṣe jẹ́ pé ‘àwọn tí ń wá Jèhófà lè lóye ohun gbogbo’? (Òwe 28:5)
12. Báwo ni ‘iṣẹ́ àṣekára àwọn arìndìn ṣe ń tán wọn lókun’? (Oníw. 10:15)
13. Ọ̀nà wo ni omidan Ṣúlámáítì gbà fi hàn pé òun jẹ́ “ọgbà tá a gbégi dínà rẹ̀,” báwo ló sì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fáwọn arábìnrin tí ò tíì lọ́kọ? (Orin Sólómọ́nì 4:12)
14. Ǹjẹ́ bí Jèhófà ṣe pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jẹ́ káwọn “mú àwọn ọ̀ràn tọ́” túmọ̀ sí pé ṣe ni Jèhófà fẹ́ kí wọ́n jọ forí korí kí wọ́n lè jọ gbà fún ara wọn lọ́tùn-ún lósì? (Aís. 1:18a)
15. Ọ̀nà wo ni Aísáyà 11:6-9 gbà ṣẹ láyé ọjọ́un, ìgbà wo ló sì máa ṣẹ ní kíkún?