ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/06 ojú ìwé 2-7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 12/06 ojú ìwé 2-7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù December: Ẹ lo ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Iwe Itan Bibeli Mi àti Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tó bá ti wà ṣáájú ọdún 1991. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! tàbí ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ míì tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ìjọ. March: Ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kẹ́ ẹ sì sapá gidigidi kẹ́ ẹ lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

◼ Ẹ jọ̀wọ́, a fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé lọ́dún 2008, ọjọ́ Saturday, March 22, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, ni Ìrántí Ikú Kristi yóò wáyé. À ń fi èyí tó yín létí lásìkò kẹ́ ẹ lè tètè ṣe àwọn ètò tó yẹ tàbí kẹ́ ẹ lè wá gbọ̀ngàn tẹ́ ẹ máa lò àtàwọn ohun èèlò mìíràn bó bá jẹ́ pé ìjọ tiyín nìkan kọ́ ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó bá wá jẹ́ pé ìjọ tiyín nìkan kọ́ ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà rí i pé àwọn ṣètò tó fìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn alákòóso gbọ̀ngàn náà láti rí i pé àwọn ìgbòkègbodò mìíràn tó bá wáyé ní sàkáání gbọ̀ngàn náà lọ́jọ́ yẹn kò ní dí àlàáfíà àti ìwàlétòlétò Ìrántí Ikú Kristi lọ́wọ́. Nítorí bí Ìrántí Ikú Kristi ti ṣe pàtàkì tó, ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó tóótun jù lọ ni kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà yan pé kó sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi, dípò kí wọ́n máa tò ó láàárín ara wọn tàbí kí wọ́n máa lo arákùnrin kan náà lọ́dọọdún. Àmọ́, bí alàgbà kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró bá wà tó lè sọ àsọyé náà, òun ni kí wọ́n yàn pé kó sọ ọ́.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Jí! (ìdìpọ̀ ti ọdún 2005)—Gẹ̀ẹ́sì

Ilé Ìṣọ́ (ìdìpọ̀ ti ọdún 2005)—Gẹ̀ẹ́sì

◼ Àwọn Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Doing God’s Will With Zeal (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, kásẹ́ẹ̀tì kan ṣoṣo ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Sún Mọ́ Jèhófà (kásẹ́ẹ̀tì mẹ́jọ ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà (kásẹ́ẹ̀tì márùn-ún ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí (kásẹ́ẹ̀tì mẹ́jọ ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? (kásẹ́ẹ̀tì márùn-ún ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

◼ Àwọn Ike Pẹlẹbẹ Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

A Satisfying Life—How to Attain It—Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ (ike pẹlẹbẹ méjì ló wà nínú ẹ̀)—Gẹ̀ẹ́sì

Sún Mọ́ Jèhófà—Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ (ike pẹlẹbẹ mọ́kànlá ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Iwe Itan Bibeli Mi—Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ (ike pẹlẹbẹ mẹ́fà ló wà nínú ẹ̀)—Gẹ̀ẹ́sì

Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?—Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ (ike pẹlẹbẹ méjì ló wà nínú ẹ̀)—Gẹ̀ẹ́sì

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?—Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ (ike méje ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

◼ Kásẹ́ẹ̀tì Fídíò Tuntun Tó Wà:

Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?—Tá A Ṣe Sínú Fídíò Kásẹ́ẹ̀tì—Èdè Àwọn Adití

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?—Tá A Ṣe Sínú Fídíò Kásẹ́ẹ̀tì, Ìdìpọ̀ 1 sí 6—Èdè Àwọn Adití

Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà—Tá A Ṣe Sínú Fídíò Kásẹ́ẹ̀tì, Ìdìpọ̀ 1 sí 8—Èdè Àwọn Adití

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́