Àwọn Ìbéèrè Tá a Máa Lò Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Bá a ṣe máa lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà fún ìkẹ́kọ̀ọ́
Kó o bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí lọ́nà tó gbámúṣé, á dáa kó o kọ nọ́ńbà sáwọn ìpínrọ̀ tó wà ní orí kọ̀ọ̀kan, títí kan àwọn ìpínrọ̀ tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú. Gbogbo ìpínrọ̀ tó bá wà nínú ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan ni kó o sì máa kà pa pọ̀. Bẹ́ ẹ bá ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ, ẹ lè jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan nígbà tó bá yẹ.
Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ka ìwé yìí ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, orí méjì ni kẹ́ ẹ máa kà lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, kẹ́ ẹ fi ọ̀rọ̀ ìṣáájú ṣe orí kìíní. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lẹ máa fi kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwé yìí, kẹ́ ẹ fi ọ̀sẹ̀ tó bá kẹ́yìn jíròrò Orí 48 tó gbẹ̀yìn pẹ̀lú àtúnyẹ̀wò ráńpẹ́ nínú ìwé yìí.
Orí 16 Ìpínrọ̀ 1 sí 6
1. Kí ni ìṣòro tí ọkùnrin tó lọ fi ẹjọ́ arákùnrin rẹ̀ sun Jésù ní?
2. Ìtàn wo ni Jésù sọ láti fi èrò tí kò tọ́ tó wà lọ́kàn ọkùnrin yẹn hàn? (Ka Lúùkù 12:16-21)
Ìpínrọ̀ 7 sí 13
3. Báwo lọ̀pọ̀ ọmọdé àtàgbà ṣe dà bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn?
4. Kí lohun tó ṣe pàtàkì ju àwọn ohun ìní tara lọ, àmọ́ kí làwọn èèyàn ń fi hàn pó ṣe pàtàkì sí wọn lónìí bí i ti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn?
5. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ dà bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ inú ìtàn Jésù yẹn?
Ìpínrọ̀ 14 sí 17
6. Kí ló túmọ̀ sí láti ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
7. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa lórí ọ̀ràn yìí?
8. Báwo ni Ọlọ́run ṣe san èrè fún Jésù nítorí pó lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀?
Orí 17 Ìpínrọ̀ 1 sí 8
1. Kí ni èèyàn lè ṣe láti ní ayọ̀?
2. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀”?
3. Kí la lè fún àwọn ẹlòmíì?
Ìpínrọ̀ 9 sí 12
4. Kí ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fún àwọn èèyàn?
5. Kí ni Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù fún àwọn èèyàn, kí sì nìdí tí Lìdíà náà fi fẹ́ láti fún wọn ní nǹkan?
Ìpínrọ̀ 13 sí 16
6. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo fífún àwọn èèyàn ní nǹkan, kí sì nìdí?
7. Kí ló mú kí obìnrin opó yẹn láyọ̀ láti fún Ọlọ́run ní gbogbo owó tó ní?
8. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ‘máa fúnni ní nǹkan nígbà gbogbo,’ kí ló sì máa yọrí sí tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀?
Orí 18 Ìpínrọ̀ 1 sí 5
1. Kí ló yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá ṣoore fún wa?
2. Kí ni ẹ̀tẹ̀, kí sì nìdí táwọn èèyàn kì í fi í sún mọ́ àwọn adẹ́tẹ̀ nígbà tí Jésù wà láyé?
3. Báwo ni Jésù ṣe ṣe sáwọn adẹ́tẹ̀?
Ìpínrọ̀ 6 sí 12
4. Kí ni Jésù sọ fáwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá tó bẹ̀ ẹ́ pé kó wo àwọn sàn, kí ló sì mú kí Jésù ṣe bẹ́ẹ̀?
5. Kí ló fi hàn pé àwọn adẹ́tẹ̀ wọ̀nyẹn gbà gbọ́ pé Jésù lè wo àwọn sàn?
6. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn adẹ́tẹ̀ yẹn lójú ọ̀nà, nígbà tí wọ́n ń lọ fara han àwọn àlùfáà?
7. Kí ló mú kí ọkùnrin ará Samáríà kan yàtọ̀ sáwọn yòókù lára àwọn mẹ́wàá tí Jésù wò sàn?
Ìpínrọ̀ 13 sí 18
8. Báwo la ṣe lè fìwà jọ ọkùnrin tó padà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù?
9. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa rántí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó bá ṣoore fún wa?
Orí 19 Ìpínrọ̀ 1 sí 5
1. Kí ni Jésù sọ nípa jíjẹ́ èèyàn àlàáfíà, àmọ́ kí ni kì í mú kó rọrùn nígbà míì láti jẹ́ èèyàn àlàáfíà?
2. Nígbà táwọn ará Samáríà kọ̀ láti gba Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lálejò, kí ni Jákọ́bù àti Jòhánù fẹ́ láti ṣe?
Ìpínrọ̀ 6 sí 12
3. Kí ni ìwé Òwe 24:29 sọ nípa gbígbẹ̀san?
4. Kí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 5:39?
5. Tí ìjàngbọ̀n bá bẹ̀rẹ̀, kí ló dára jù láti ṣe, kí sì nìdí?
Ìpínrọ̀ 13 sí 17
6. Kí ni Òwe 26:17 sọ, báwo sì ni ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí ṣe bá ọ̀ràn ẹni tó lọ dá sí ìjà àwọn ẹlòmíràn mu?
7. Kí làwọn èèyàn sábà máa ń ṣe nígbà tí ìjà bá bẹ̀rẹ̀, àmọ́ kí ló yẹ kí Kristẹni kan ṣe, kí sì nìdí?
Orí 20 Ìpínrọ̀ 1 sí 7
1. Kí ni ìṣarasíhùwà Jésù sí àwọn tó máa ń fẹ́ wà nípò àkọ́kọ́ ní gbogbo ìgbà?
2. Ìtàn wo ni Jésù sọ, kí sì nìdí tó fi sọ ọ́?
3. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Jésù kọ́ wa nínú ìtàn náà?
4. Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá ń gbìyànjú láti wà nípò àkọ́kọ́?
Ìpínrọ̀ 8 sí 15
5. Báwo ni fífẹ́ láti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ ṣe dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn àpọ́sítélì Jésù lójú ọ̀nà nígbà tí wọ́n ń lọ sí Jerúsálẹ́mù?
6. Kí ni Jésù sọ pé ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ gbọ́dọ̀ máa ṣe?
7. Báwo la ṣe lè máa ṣe bí ẹrú síra wa?
Orí 21 Ìpínrọ̀ 1 sí 10
1. Kí ló túmọ̀ sí láti máa fọ́nnu, kí ni èrò rẹ nípa àwọn èèyàn tó máa ń fọ́nnu?
2. Ìtàn wo ni Jésù sọ nípa Farisí àti agbowó orí kan?
3. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù kọ́ wa nínú ìtàn yìí?
Ìpínrọ̀ 11 sí 19
4. Ìgbà wo ni Pétérù fọ́nnu, báwo sì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí?
5. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fọ́nnu nípa ara wa?
6. Ta lẹnì kan ṣoṣo tá a lè fi fọ́nnu tàbí ká fi ṣògo, kí sì nìdí?
Orí 22 Ìpínrọ̀ 1 sí 6
1. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ tó wà nínú Mátíù 5:37?
2. Kí làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ikú Jésù?
Ìpínrọ̀ 7 sí 13
3. Kí ló burú nínú ohun tí Ananíà àti Sáfírà ṣe, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí wọn?
4. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ananíà àti Sáfírà?
Ìpínrọ̀ 14 sí 18
5. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa purọ́?
6. Ìgbà wo ló lè ṣe wá bí i pé ká purọ́?
7. Báwo ni Bíbélì ṣe kìlọ̀ fún wa pé kò yẹ ká máa purọ́?
Orí 23 Ìpínrọ̀ 1 sí 8
1. Níbo ni Jésù wà nígbà tí wọ́n gbé ọkùnrin kan tó lárùn ẹ̀gbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀?
2. Kí ló dé tí kò fi rọrùn láti gbé ọkùnrin aláìsàn yẹn dé ibi tí Jésù wà, báwo ni wọ́n sì ṣe wá gbé e débẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín?
3. Kí ni Jésù ṣe fún ọkùnrin tó ní àrùn ẹ̀gbà yẹn?
Ìpínrọ̀ 9 sí 14
4. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe láti wo ọkùnrin tó ní àrùn ẹ̀gbà yẹn sàn?
5. Báwo ni gbogbo èèyàn ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀?
Ìpínrọ̀ 15 sí 18
6. Kí ló fà á táwọn kan fi máa ń ṣàìsàn púpọ̀ ju àwọn míì lọ?
7. Ọ̀nà kan ṣoṣo wo ni Ọlọ́run máa gbà mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, irú ìlera wo la sì máa ní lẹ́yìn tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá ti kúrò lára wa?
Orí 24 Ìpínrọ̀ 1 sí 13
1. Kí ló lè mú kí ẹnì kan di olè?
2. Ta ló kọ́kọ́ di olè, kí ló sì jí?
3. Èrò tí kò dára wo la gbọ́dọ̀ máa yẹra fún?
4. Kí ni èrò búburú tó wà lọ́kàn Júdásì Ísíkáríótù mú kó ṣe?
Ìpínrọ̀ 14 sí 21
5. Báwo ni Ákánì ṣe di olè?
6. Báwo ni Dáfídì àti ọmọ rẹ̀ Ábúsálómù ṣe jí ohun tí kì í ṣe tiwọn?
7. Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo onírúurú olè jíjà?
8. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní di olè?
Orí 25 Ìpínrọ̀ 1 sí 8
1. Kí ló fà á tá a fi máa ń ṣàṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?
2. Àwọn nǹkan búburú wo ni Sọ́ọ̀lù ṣe, kí sì nìdí tó fi ṣe é?
Ìpínrọ̀ 9 sí 15
3. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù lójú ọ̀nà, nígbà tó fẹ́ lọ fòfin mú àwọn Kristẹni?
4. Irú ẹni wo ni Sọ́ọ̀lù wá dà nígbà tó yá, àwọn nǹkan rere wo ló sì gbé ṣe?
5. Ta lẹni tó ń fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe ohun tó máa mú káwa èèyàn ṣe nǹkan burúkú?
Ìpínrọ̀ 16 sí 20
6. Ìsapá wo ni gbogbo wa ní láti ṣe?
7. Kí nìdí tí Jésù fi fẹ́ràn àwọn èèyàn tó ti ṣe ohun búburú tẹ́lẹ̀?
8. Nígbà tí Bíbélì bá fi hàn pé ohun tá à ń ṣe kò dára, kí ló yẹ ká ṣe?
Orí 26 Ìpínrọ̀ 1 sí 9
1. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù di ọmọlẹ́yìn Jésù, kí làwọn èèyàn ṣe fún un?
2. Òtítọ́ wo ni Jésù sọ fáwọn èèyàn látinú Bíbélì tó mú kí wọ́n bínú?
3. Kí làwọn èèyàn yẹn gbìyànjú láti ṣe fún Jésù, àmọ́ ṣé ìyẹn dá Jésù dúró pé kó má wàásù fún wọn?
Ìpínrọ̀ 10 sí 14
4. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù ṣe lọ́jọ́ Sábáàtì?
5. Inú ta ló dùn síṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, àmọ́ àwọn wo ni inú wọn ò dùn?
6. Ìpinnu wo ni gbogbo wa ní láti ṣe?
7. Ta lẹni tó ń mú kó nira fún wa láti máa ṣe rere?
Ìpínrọ̀ 15 sí 18
8. Àwọn wo ni ayé tó kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù?
9. Kí nìdí tó fi ṣòro gan-an láti máa ṣe ohun rere?
10. Ìlérí wo ló yẹ kó máa fún wa lókun láti máa ṣohun tí Ọlọ́run fẹ́?
Orí 27 Ìpínrọ̀ 1 sí 5
1. Kí nìdí táwọn èèyàn fi fẹ́ láti jọ́sìn Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, àmọ́ kí ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sọ, kí ni wọ́n sì ṣe?
2. Àwọn ọlọ́run wo lọ̀pọ̀ èèyàn ń jọ́sìn?
3. Ta ni ọlọ́run ayé yìí, kí ló sì ń mú káwọn èèyàn máa ṣe?
Ìpínrọ̀ 6 sí 13
4. Àṣẹ wo ni Ọba Nebukadinésárì pa, kí sì nìdí táwọn Hébérù mẹ́ta yẹn fi kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣẹ náà?
5. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jèhófà ṣe, ipa wo nìyẹn sì ní lórí Ọba Nebukadinésárì?
Ìpínrọ̀ 14 àti 15
6. Ǹjẹ́ o lè dárúkọ èyíkéyìí lára àwọn ère tàbí àwòrán táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ lónìí?
7. Kí ló máa jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹn sáwọn ère táwọn èèyàn ń júbà fún lónìí?
Orí 28 Ìpínrọ̀ 1 sí 5
1. Kí nìdí tó fi máa ń nira nígbà míì láti mọ ẹni tó yẹ ká ṣègbọràn sí?
2. Ìtọ́ni wo ni Bíbélì fáwọn ọmọ?
3. Kí nìdí tí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò fi kọ̀ láti tẹrí ba fún ère tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀?
4. Kí làwọn àpọ́sítélì pinnu láti ṣe nígbà tí wọ́n kojú ọ̀ràn nípa ẹni tó yẹ kí wọ́n ṣègbọràn sí?
Ìpínrọ̀ 6 sí 10
5. Ta ni olórí ìjọba tó ń ṣàkóso nígbà ayé Jésù, àwọn nǹkan rere wo làwọn ìjọba sì sábà máa ń ṣe?
6. Kí ni Jésù sọ nípa sísan owó orí, kí sì nìdí tí ìtọ́ni yẹn fi yẹ bẹ́ẹ̀?
Ìpínrọ̀ 11 sí 18
7. Kí nìdí tí tọmọdé tàgbà fi gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí àṣẹ ìjọba àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba?
8. Ìgbà wo làwọn Kristẹni tòótọ́ ò ní ṣègbọràn sáwọn àṣẹ kan, kí sì nìdí?
Orí 29 Ìpínrọ̀ 1 sí 10
1. Kí ló fi hàn pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ṣíṣe àpèjẹ, àmọ́ irú àwọn àpèjẹ wo ni inú Ọlọ́run ò dùn sí?
2. Ayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjì wo ni Bíbélì sọ nípa ẹ̀?
3. Ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi àwọn àpèjẹ yìí?
Ìpínrọ̀ 11 sí 15
4. Kí lo rò pé Bíbélì ń sọ fún wa nípa àpèjẹ ọjọ́ ìbí?
5. Déètì wo làwọn èèyàn yàn láti máa ṣe ọjọ́ ìbí Jésù, àmọ́ kí ló fi hàn pé kò lè jẹ́ ìgbà yẹn ni ìbí Jésù bọ́ sí?
Ìpínrọ̀ 16 àti 17
6. Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì?
7. Báwo la ṣe lè rí i dájú pé inú Ọlọ́run dùn sí àpèjẹ wa? (Jòhánù 17:16; 2 Kọ́ríńtì 6:14; 1 Pétérù 4:3)
Orí 30 Ìpínrọ̀ 1 sí 9
1. Kí ló fà á tí Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù fi bẹ̀rù?
2. Kí làwọn nǹkan tó mú kí Pétérù sẹ́ Jésù?
Ìpínrọ̀ 10 sí 16
3. Ìgbà mélòó ni Pétérù sẹ́ Jésù, báwo ló sì ṣe ṣẹlẹ̀?
4. Báwo làwa náà ṣe lè dójú kọ irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù yẹn?
5. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe bẹ̀rù ká má sì kábàámọ̀ bí i ti Pétérù?
Orí 31 Ìpínrọ̀ 1 sí 7
1. Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Bíbélì sọ fáwọn tó wà nínú ìbànújẹ́ àtàwọn tó dá nìkan wà?
2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù jìyà, kí ló dáa lójú?
3. Ọ̀nà wo la gbà dà bí àgùntàn, ìtàn wo sì ni Jésù sọ nípa àgùntàn kan tó sọnù?
Ìpínrọ̀ 8 sí 12
4. Ta ló dà bí olùṣọ́ àgùntàn tí Jésù sọ nínú ìtàn rẹ̀, kí sì nìdí tí rírí tá ò lè rí Ọlọ́run sójú ò ṣe dí wa lọ́wọ́ láti gbà pé ó lè bójú tó wa?
5. Báwo ni Sáàmù 23 ṣe fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
Ìpínrọ̀ 13 sí 15
6. Kí nìdí táwọn àgùntàn Jèhófà ò fi ní láti bẹ̀rù?
7. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn olóòótọ́, báwo sì nìyẹn ṣe gbọ́dọ̀ nípa lórí èrò wa nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́?