Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá ó lò lóṣù February 19 sí March 18: A ó ṣe àkànṣe ìpínkiri ìwé àṣàrò kúkúrú Kingdom News No. 37 tó ní àkọlé náà “Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!” March 19 sí 31: Ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kẹ́ ẹ sì sapá gidigidi kẹ́ ẹ lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn títí kan àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ wa mìíràn àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kẹ́ ẹ lè fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. June: Ẹ lo ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.
◼ Ní gbàrà táwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! bá ti dé ni kí ìjọ jẹ́ kí àwọn ará rí i gbà. Èyí á jẹ́ káwọn akéde lè ti kà á kó tó di pé wọ́n á fi ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.
◼ Kí alága àwọn alábòójútó tàbí ẹnì kan tó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ti oṣù December, January àti February. Bó bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀. Ẹ wo ìwé tó ṣàlàyé nípa bó ṣe yẹ ká bójú tó àkáǹtì ìjọ, ìyẹn Instructions for Congregation Accounting (S-27).
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2007 ni, “O Lè Nífọ̀kànbalẹ̀ Nínú Ayé Tó Kún fún Ìdààmú Yìí!” Ẹ wo ìfilọ̀ tó jọ èyí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2006.
◼ A ti fi ìwé àsọyé tuntun (S-31 10/06) tẹ́ ó máa fi sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ. Kí alága àwọn alábòójútó jọ̀wọ́ rí i pé ìwé àsọyé tuntun tó ní déètì October 2006 lára ni ẹni tó máa sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí lò. Ẹ fa gbogbo ìwé àsọyé Ìrántí Ikú Kristi tẹ́ ẹ bá ní lọ́wọ́ tó yàtọ̀ sí èyí tá a kọ 10/06 sí lára ya.
◼ Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:
Watch Tower Publications Index (Ìdìpọ̀ ti ọdún 2001 sí 2005)—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Àwo CD Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:
Kọrin Ìyìn sí Jehofah—MP3 (Èyí tí wọ́n fi dùùrù kọ)
◼ Àwọn Àwo DVD Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé—Lórí Àwo DVD —Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà
Noah Walked With God—David Trusted in God—Lórí Àwo DVD—Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà