Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
TỌKÀNTỌKÀN làwa náà fi ń gbàdúrà sí Ọlọ́run bí Jésù ṣe gbà á pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” Ọ̀nà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń gbé ìgbésí ayé wa ń fi hàn pé lóòótọ́ lohun tá à ń béèrè nínú àdúrà yẹn jẹ wá lógún. A mọ̀ pé a ní ojúṣe míì yàtọ̀ sí mímọ̀ tá a mọ orúkọ Ọlọ́run. Ìyẹn ni pé gbogbo àǹfààní tá a bá ní la gbọ́dọ̀ fi máa gbórúkọ náà ga. Kò sí àní àní pé, ọlá tó ju ọlá lọ tí gbogbo wa ní ni jíjẹ́ tá a jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Mát. 6:9; Aís. 43:10.
Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 110:3 ti wí, tinútinú làwọn èèyàn Jèhófà fi ń ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe. Kí nìdí tí tọmọdé tàgbà láti onírúurú ibi fi ń lo ara wọn fún iṣẹ́ ìwàásù tó bẹ́ẹ̀? Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà lohun àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà ni ìpinnu tí wọ́n ṣe láti fi tọkàntọkàn ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Diutarónómì 6:5, 6 pa á láṣẹ pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú ‘gbogbo ọkàn àyà àti gbogbo ọkàn àti gbogbo okunra wa.’ Ìfẹ́ àtọkànwá yìí ló ń mú ká lè máa lo àkókò, agbára àti dúkìá wa láti máa fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó ní nínú ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa débi tí agbára wa bá gbé e dé.
Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí gbogbo èèyàn ló jẹ́ kó sọ pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ayé. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà ìwàkíwà tí wọ́n ń hù kí wọ́n sì padà sọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wọn kí wọ́n bàa lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (2 Pét. 3:9) Jèhófà sọ pé: “Èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí padà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó ní tòótọ́.” (Ìsík. 33:11) Nígbà tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn bíi tiwa, ṣe ni Jèhófà ń lò wá láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó dájú pé òtítọ́ yìí wà lára ohun tó ń jẹ́ ká túbọ̀ máa láyọ̀ ká sì máa nítẹ̀ẹ́lọ́rùn bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí.
Ọwọ́ tá a fi ń mú Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tún máa ń jẹ́ ká lè fi bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó hàn. Bí kì í bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì, à bá tí mọ Ọlọ́run ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àǹfààní tá a ní láti sún mọ́ ọn gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù 4:8 ṣe rọ̀ wá pé ká ṣe. À bá sì má mọ ìdí tí Ọlọ́run ṣe dá wa sáyé àtohun tó ń bọ́ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Kò sẹ́nikẹ́ni nínú wa tíì bá mọ̀ pé baba ńlá gbogbo wa, ìyẹn Ádámù ló kó wa sínú àwọn ìṣòro tá à ń bá yí wọ̀nyí. (Róòmù 5:12) Kò sì sí bá ò bá ṣe mọ̀ pé nítorí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí wa ló ṣe fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo rà wá padà. Ìyẹn bẹ́ẹ̀, àìmọye ọ̀nà míì ni Jèhófà ti fi fún wa lára ìmọ̀, ọgbọ́n àti òye rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀bùn yìí jọ wá lójú, ìyẹn Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mí sí? Bá a bá mọrírì àgbàyanu ẹ̀bùn yìí, ńṣe la ó máa ‘ra àkókò padà,’ tá ó máa wá àkókò láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá ó máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tá ó sì máa ṣe àṣàrò lé e lórí. (Éfé. 5:15, 16; Sáàmù 1:1-3) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa ṣe wá bíi pé ńṣe là ń fi àkókò tá a fi ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ ṣòfò. Dípò ìyẹn, ńṣe ni ká jẹ́ kí nínífẹ̀ẹ́ tá a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa mú ká máa gbé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹ̀ wò, èyí tó máa jẹ́ ká lè ṣàlékún òye wa nípa rẹ̀, nípa báyìí, ìfẹ́ tá a ní fún un á máa jinlẹ̀ sí i.
A ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà, ó sọ gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀ títí kan kálukú wa yìí dẹni ègún láìsọ́nà àbáyọ. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí Ọlọ́run ti lágbára láti ṣe ọ̀nà àbáyọ fáráyé, ó ṣọ̀nà àbáyọ náà nípa ṣíṣe àwọn nǹkan kan, èyí tó máa jẹ́ kí ohun tó ní lọ́kàn láti fi ilé ayé wa yìí ṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún padà di ṣíṣe.—Jẹ́n. 3:15.
Ó dájú pé kálukú wa ló máa rí i pé òun ṣe ipa tòun kí orúkọ ńlá Ọlọ́run wa náà bàa lè di mímọ́. Bí ìmọ̀ tá a ní nípa bí Jèhófà Ọlọ́run wa ṣe jẹ́ àgbàyanu tó ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ló ṣe ń wù wá tó láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ká sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò tó ń lò láti mú kí orúkọ ńlá rẹ̀ àtohun tó máa ṣe di mímọ̀ fáráyé. Lásìkò yìí, ó dá wa lójú pé kò ní yé tì wá lẹ́yìn, á sì máa fojúure hàn sí wa àti pé á fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun.
Gbogbo àwa tá a wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹni ọ̀wọ́n lẹ̀yin ará jẹ́ sí wa, lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà. A sì tún fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé a mọrírì bẹ́ ẹ ṣe ń sapá láti máa lo ìwọ̀nba àkókò tó ṣẹ́ kù yìí láti rí i pé ẹ wàásù ìhìn rere náà fún gbogbo èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó kí “ìpọ́njú ńlá” tó wọlé dé. (Ìṣí. 7:14) Bẹ́ ẹ ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń jẹ́ káwọn èèyàn lè rí ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Kristi, èyí tó ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun gbà, bẹ́yin náà ṣe rí i gbà.—Jòhánù 17:3.
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà