Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá ó lò lóṣù May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn títí kan àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ wa mìíràn àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kẹ́ ẹ lè fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. June: Ẹ lo ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi—Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọ́run Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.”
◼ Bí ẹnì kan bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣe ọrẹ tó máa fi sínú àpótí ọrẹ ní àpéjọ àgbègbè láti fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ yíká ayé tàbí tó fẹ́ fi ọrẹ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, “Watch Tower Society” ni kẹ́ni náà kọ sórí sọ̀wédowó pé kí wọ́n sanwó náà fún.
◼ Kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà jíròrò lẹ́tà July 6, 2006, èyí tó sọ nípa bí wọ́n ṣe lè múra sílẹ̀ de àjálù, kí wọ́n sì rí i pé àdírẹ́sì ibi tí akéde kọ̀ọ̀kan ń gbé wà lọ́wọ́ àwọn. Láwọn àdúgbò tí àjálù ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀, kẹ́ ẹ ri í pé ẹ béèrè ọ̀nà míì tẹ́ ẹ lè gbà kàn sí wọn bí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. Bákan náà, yàtọ̀ sí ọ̀ràn pàjáwìrì, ó tún máa ń dáa táwọn akéde bá lè máa fi tó alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wọn létí bí wọ́n bá fẹ́ rìnrìn àjò fún àkókò gígùn, bóyá lásìkò tí wọ́n bá gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, lásìkò tí wọ́n bá wà ní ilé ìwòsàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.