Àwọn Ìfilọ̀
◼ July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi—Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọ́run Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la ó lò. Ká sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá bá onítọ̀hún pàdé. Báwọn tẹ́ ẹ fẹ́ fún ní ìwé náà bá sọ pé àwọn ti ní in tẹ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè jàǹfààní látinú ẹ̀ nípa fífi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn wọ́n ní ṣókí. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Bí ẹni náà bá fìfẹ́ hàn, kẹ́ ẹ fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? kẹ́ ẹ lè fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.
◼ Níwọ̀n bí oṣù September ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Láti oṣù September lọ, ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo èèyàn tí àwọn alábòójútó àyíká máa bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ni, “Kí Ló Fi Hàn Pé Òótọ́ Lọ̀rọ̀ Inú Bíbélì?”
◼ A dábàá pé kẹ́ ẹ máa fi àwọn ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán, lóṣù kan ṣáájú déètì tí akéde náà á fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀. Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn fọ́ọ̀mù náà pé pérépéré. Báwọn tó fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà ò bá lè rántí ọjọ́ tí wọ́n ṣèrìbọmi, kí wọ́n fojú bu déètì kan, kí wọ́n sì tọ́jú déètì náà pa mọ́. Kí akọ̀wé kọ déètì náà sórí káàdì Congregation’s Publisher Record (S-21), ìyẹn àkọsílẹ̀ akéde ìjọ.
◼ Ní August 31, 2007 tàbí kó máà pẹ́ sígbà yẹn, kí ẹ ka gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́, bá a ti ń ṣe lọ́dọọdún. Ìṣirò yìí jọ èyí tí olùṣekòkáárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe lóṣooṣù nípa kíka àwọn ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Kẹ́ ẹ kọ iye tí wọ́n jẹ́ sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18). Ẹ ní kí (àwọn) ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn sọ àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ fún yín. Akọ̀wé ìjọ tó ń ṣe kòkáárí ni kó bójú tó ìṣirò ọlọ́dọọdún náà. Akọ̀wé àti alága àwọn alábòójútó ìjọ tó ń ṣe kòkáárí ni kó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo ìjọ tó ń ṣe kòkáárí yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory mẹ́ta-mẹ́ta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta láti fi ṣírò ìwé tó wà lọ́wọ́.
◼ A fi fọ́ọ̀mù nípa àwọn tí ò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, ìyẹn Literacy Report, méjì-méjì ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Bẹ́ ẹ bá ti kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù méjèèjì, ẹ fi ẹ̀dà kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní August 1. Kẹ́ ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì ìjọ.