Àpótí Ìbéèrè
◼ Ìgbà wo ló yẹ ká máa kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì láti béèrè ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ Bíbélì àti ìjọsìn wa, báwo ló sì ṣe yẹ ká máa kọ irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀?
Ọdọọdún là ń gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún lẹ́tà, tẹ́ ẹ̀ ń kọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ti Nàìjíríà níbí, lórí onírúurú ọ̀ràn tàbí èyí tẹ́ ẹ fi ń béèrè fún ìmọ̀ràn nípa àwọn ìṣòro kan. Nígbà míì sì rèé orí tẹlifóònù la ti ń gbọ́ àwọn ìbéèrè míì. A láyọ̀ láti ran àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá nílò wa. Àmọ́ ṣá o, a ti rí i pé lọ́pọ̀ ìgbà ẹ lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí láì kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì rárá. Púpọ̀ lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí la ti dáhùn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ sínú àwọn ìwé wa, ó sì lè jẹ́ èyí táwọn alàgbà ìjọ yín lè bójú tó, torí àwọn ló mọ ohun tó bá àdúgbò yín mu.
Nítorí náà, a dá a lábàá pé tẹ́ ẹ bá nílò ìdáhùn sáwọn ìbéèrè kan, ẹ kọ́kọ́ wá a nínú àwọn ìwé wa nípa lílo ìwé atọ́ka ìyẹn, Watch Tower Publications Index. Kẹ́ ẹ wo apá tó jíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú ìwé atọ́ka náà. Tá a bá tẹ̀ lé àbá yìí, á jẹ́ kí olúkúlùkù lè máa ṣe ojúṣe rẹ̀ tó bá dọ̀ràn ṣíṣe ìpinnu tó bá ìlànà Jèhófà mu. (Gál. 6:5) Tẹ́ ò bá mọ bá a ṣe ń fi atọ́ka, ìyẹn Index, wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè, ẹ kàn sáwọn alàgbà ìjọ yín tàbí alábòójútó àyíká yín fún ìrànlọ́wọ́.
Tó bá wá jẹ́ pé ẹ nílò ìmọ̀ràn láti yanjú ìṣòro kan, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ kọ́kọ́ lọ bá àwọn alàgbà ìjọ yín ná. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí mọ̀ yín dáadáa, wọ́n sì mọ bí nǹkan ṣe rí fun yín; àwọn gan-an ló lè fun yín ní ìmọ̀ràn tẹ́ ẹ nílò látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Fèrò yìí wé Òwe 27:23) Ẹ rántí pé torí ìrànlọ́wọ́ tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa ni Jèhófà ṣe ṣètò àwọn alàgbà sínú ìjọ.—Aísá. 32:1, 2; Jer. 23:4.
Tẹ́ ẹ bá ti wá gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn alàgbà, síbẹ̀ tí àlàyé tàbí ìmọ̀ràn wọn ò yanjú ìṣòro ọ̀hún, tẹ́ ẹ sì rí i pé ẹ nílò ìrànlọ́wọ́ síwájú sí i, ìgbà yẹn gan-an lẹ lè fi tó wa létí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ohun tó máa dáa jù ni pé kẹ́ ẹ kọ lẹ́tà láti ṣàlàyé ọ̀ràn náà lọ́nà tó máa gbà yéni. Tẹ́ ẹ bá ń kọ̀wé, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rí i dájú pé ẹ kọ orúkọ yín, orúkọ ìjọ tẹ́ ẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ àti orúkọ àwọn tí ọ̀ràn náà kàn gbọ̀ngbọ̀n sínú lẹ́tà náà. A kì í sábà gbé àwọn lẹ́tà tí kò lórúkọ yẹ̀ wò. A ò ní fẹ́ kẹ́ ẹ máa kọ̀wé sí wa lórí àwọn ọ̀ràn ká-sọ-pé, tí kò ṣẹlẹ̀. Ẹ ṣàlàyé bí ọ̀ràn náà ṣe rí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ẹ ṣàlàyé àwọn nǹkan tẹ́ ẹ ti ṣe láti yanjú ìṣòro ọ̀hún, kẹ́ ẹ sì kọ ìdí tẹ́ ẹ fi rò pé ìṣòro ọ̀hún ò tíì yanjú síbẹ̀. A máa gbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn náà fun yín. Tó bá jẹ́ pé ìmọ̀ràn táwọn alàgbà fun yín lẹ fẹ́ torí ẹ̀ kọ̀wé sí wa, ẹ má ṣe gbàgbé láti fún wọn ní ẹ̀dà lẹ́tà tẹ́ ẹ fẹ́ fi ránṣẹ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe pè wá sórí fóònù, àyàfi tọ́ràn náà bá jẹ́ kánjúkánjú.