Bí Ìdílé Ṣe Lè Jọ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
1 Jèhófà ò yéé rán àwọn olórí ìdílé létí pé ojúṣe wọn ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn. Ó jẹ́ kí Ábúráhámù mọ̀ pé ojúṣe òun ni pé kóun kọ́ àwọn ará ilé òun kí wọ́n bàa lè máa “pa ọ̀nà Jèhófà mọ́.” (Jẹ́n. 18:19) Ọlọ́run pa á láṣẹ fáwọn tó jẹ́ òbí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ wọn ní gbogbo ìgbà. (Diu. 6:6, 7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn olórí ìdílé tí wọ́n jẹ́ Kristẹni láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Ṣé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìdílé rẹ nípa ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé? Tó bá jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn òbí ló ṣì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, òun ni kó máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Tẹ́ ò bá tíì bímọ, kí ìwọ àti ìyàwó rẹ jùmọ̀ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pa pọ̀.
2 Ìgbà Tó Yẹ Kẹ́ Ẹ Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Sí: Ohun tó dáa jù ni pé kí gbogbo ìdílé jọ fohùn ṣọ̀kan lórí àkókò tó rọrùn jù lọ tí wọ́n á fẹ́ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Àwọn kan máa ń gbádùn ẹ̀ gan-an láàárọ̀ kùtù nígbà tára ṣì dá, alẹ́ làwọn kan sì máa ń fẹ́ ṣe é torí ẹsẹ̀ gbogbo wọ́n máa ń pé sílé. Àwọn ìdílé kan ti rí i pé ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ló máa dáa káwọn máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé; ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ sì làwọn míì fi ń ṣe é lójoojúmọ́. Èyí ó wù ó jẹ́, rí i dájú pé ìwọ̀n àkókò tẹ́ ẹ fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ò gùn jù fún ọjọ́ orí àwọn ọmọ yín. Òótọ́ ni pé ó dáa kéèyàn mọwọ́ yí padà, síbẹ̀ ó yẹ kí ètò tó jíire wà tẹ́ ẹ ó máa tẹ̀ lé. Rí i dájú pé kò sẹ́ni tó ń pa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ, kí gbogbo ìdílé sì máa fìtara lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
3 Ìwé Tẹ́ Ẹ Máa Lò: Ẹ lè jọ máa múra sílẹ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Tẹ́ ẹ bá láwọn ọmọdé, ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà tàbí Ìwé Ìtàn Bíbélì Mi máa wúlò gan-an. Táwọn ọmọ yín bá ti di géńdé, ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé tàbí àpilẹ̀kọ tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! máa ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an ni. Bí ọ̀ràn pàtàkì kan bá ṣẹlẹ̀ tó ń fẹ́ àbójútó, bóyá tó dá lórí iléèwé àwọn ọmọ tàbí ìwà táwọn ọmọ ń hù, wá àpilẹ̀kọ tó bá a mu kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Jẹ́ kí olúkúlùkù ti mọ ìwé tẹ́ ẹ máa lò kó tó dọjọ́ tẹ́ ẹ máa ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ẹ padà sórí àpilẹ̀kọ tẹ́ ẹ̀ ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín tẹ́lẹ̀. Rí i dájú pé gbogbo àwọn tó mọ̀wé kà nínú ìdílé rẹ ló ní Bíbélì àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ máa kà. Táwọn òbí ò bá tiẹ̀ mọ̀wé tàbí tó jẹ́ pé tá-tà-tá ni wọ́n mọ̀, àwọn ọmọ wọn lè máa kà á sí wọn létí. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ má ṣe tẹ́ńbẹ́lú àwọn òbí yín torí pé wọn ò kàwé. Ẹ rántí pé Éfésù 6:2 sọ pé: “‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí.”
4 Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Náà Múná Dóko Kó sì Gbádùn Mọ́ni: Jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gbádùn mọ́ni, síbẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ àsìkò eré, kí ìtọ́ni táwọn ọmọ ń rí gbà lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé kì í ṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn, kì í sì í ṣe ìbéèrè àti ìdáhùn ní tààràtà. Àsìkò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó gbádùn mọ́ni ló yẹ kó jẹ́! Àwọn ìbéèrè tó máa mú kókó pàtàkì jáde àtèyí tó máa jẹ́ káwọn ọmọ sọ tinú wọn ló yẹ ká máa lò nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ẹni tó ń darí ẹ̀ kò gbọ́dọ̀ máa dá ọ̀rọ̀ náà sọ. Kò sì gbọ́dọ̀ wá sọ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà di àsìkò táá máa báwọn ọmọ wí tàbí táá máa fìyà jẹ wọ́n.
5 Ìdí tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ni pé, a fẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà pọ̀ sí i, ká lè ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa, ká sì lè máa fàwọn nǹkan tá à ń kọ́ látinú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa sílò. Máa ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mọrírì àwọn ohun ribiribi tí Jèhófà ń ṣe fún wa. Rí i dájú pé wọ́n lóye àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ̀ ń kà. Jẹ́ kí wọ́n mọ báwọn ìsọfúnni wọ̀nyí ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní tó, kí wọ́n lè ṣe àwọn ìyípadà tó bá yẹ nínú ìwà wọn.
6 Tẹ́ ò bá tíì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ẹ ò ṣe bẹ̀rẹ̀ kóṣù yìí tó parí? Bó o ti ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà nínú àdúrà pé kó ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ yín nìṣó, máa retí ìbùkún rẹ̀ lórí ìdílé rẹ bó o ti ń kọ́ wọn láti “pa ọ̀nà Jèhófà mọ́.”