ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/08 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 3/08 ojú ìwé 3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù March: Ẹ lo ìwé Kí ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Ẹ sapá lákànṣe láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fìfẹ́ hàn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n sì tún wá gbọ́ àkànṣe àsọyé àmọ́ tí wọn kì í wá sípàdé ìjọ déédéé. Ìdí tẹ́ ẹ fi fẹ́ padà bẹ̀ wọ́n wò ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. June: Ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà.

◼ Kí gbogbo ìjọ tètè máa fún àwọn akéde láwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde gbàrà tó bá ti tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè dojúlùmọ̀ àwọn ìwé ìròyìn ọ̀hún kí wọ́n tó lò wọ́n lóde ẹ̀rí.

◼ Kí ẹnì kan tí alága àwọn alábòójútó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ láwọn oṣù December, January àti February. Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kan ṣe àyẹ̀wò yìí tẹ̀ léra o. Bó bá ti parí àyẹ̀wò náà, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó lóṣù tó ń bọ̀.—Ẹ wo ìwé tó ṣàlàyé nípa bó ṣe yẹ ká bójú tó àkáǹtì ìjọ, ìyẹn Instructions for Congregation Accounting (S-27).

◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpẹ́jọ àgbègbè ọdún 2008 ni “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Wa.” Àwọn ìsọfúnni tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣètò bá a ṣe máa wá sí gbogbo apá tó máa wà ní àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí máa fara hàn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù April. Tó o bá máa tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ níbi iṣẹ́ kó o lè wà níbẹ̀ lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, má fi falẹ̀ rárá.

◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2008 ni “Ta Ló Kúnjú Ìwọ̀n Láti Ṣàkóso Aráyé?” Ẹ wo ìfilọ̀ tó jọ èyí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2007.

◼ Ní kété lẹ́yìn Ìrántí Ikú Kristi, ẹ kọ iye àwọn èèyàn tó bá wá àti iye àwọn tó bá jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ sórí káàdì tá a ti ṣètò pé kẹ́ ẹ máa kọ ọ́ sí, ìyẹn Memorial Report (S-7), tàbí kẹ́ ẹ kọ ọ́ sínú lẹ́tà, kẹ́ ẹ sì fi ránṣẹ́ sí wa. Bó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ló jọ ṣe Ìrántí Ikú Kristi pa pọ̀, ìjọ kan ṣoṣo ni kó kọ àròpọ̀ iye àwọn tó bá wá àti àròpọ̀ iye àwọn tó bá jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ, kí wọ́n wá kọ orúkọ àwọn ìjọ yòókù sínú káàdì tàbí lẹ́tà náà, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí wa.

◼ Kí gbogbo ìjọ máà gbàgbé láti fi àkókò tí wọ́n á máa ṣe àwọn ìpàdé ìjọ bẹ̀rẹ̀ láti January 1, 2008 ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Kí akọ̀wé ìjọ lo káàdì tá a fi ń kọ àwọn ìsọfúnni nípa àwọn ìpàdé ìjọ ìyẹn Congregation Meeting Information (S-5). A ti fi ẹ̀dà méjì káàdì yìí ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́