Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 28, 2008. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ March 3 sí April 28, 2008, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sì darí rẹ̀ fún ọgbọ̀n ìsẹ́jú.
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti mú ọ̀rọ̀ wa látibi tí wọ́n ti yanṣẹ́ fún wa, báwo la sì ṣe lè ṣe èyí? [be-YR ojú ìwé 234 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 235 ìpínrọ̀ 1]
2. Kí nìdí tí ìbéèrè fi ṣe pàtàkì nígbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 236 ìpínrọ̀ 1 sí 5]
3. Báwo làwọn ìbéèrè wa ṣe lè ran àwọn olùgbọ́ wa lọ́wọ́ láti ronú lórí kókó ẹ̀kọ́ kan? [be-YR ojú ìwé 237 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 1]
4. Nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, kí nìdí tí fífi ọgbọ́n lo ìbéèrè fi ṣe pàtàkì láti mú káwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde? (Òwe 20:5; Mát. 16:13-16; Jòh. 11:26) [be-YR ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 3 sí 5]
5. Àǹfààní wo ló wà nínú lílo àfiwé tààrà nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? (Jẹ́n. 22:17; Jer. 13:11) [be-YR ojú ìwé 240 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Kí la lè rí kọ́ látinú bí òtòṣì opó kan ṣe fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn àti ohun tí Jésù sọ nípa ọrẹ ọ̀hún? (Máàkù 12:41-44) [w89-YR 10/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3]
7. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ran àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ lóde òní? (Jòh. 14:25, 26) [be-YR ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2 àti 3]
8. Kí ni àǹfààní tó ga jù lọ tá a lè rí látinú ìwé kíkà? [be-YR ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 3]
9. Kí ni ìkẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1]
10. Kí la lè rí kọ́ látinú ìwé Lúùkù? Ṣàlàyé. [w89-YR 11/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 sí 5]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Kí nìdí tí Jésù fi tọ́ ọkùnrin kan tó pè é ní “Olùkọ́ Rere” sọ́nà? (Máàkù 10:17, 18) [w08-YR 2/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Máàkù”]
12. Àpèjúwe wo ni Jésù fi igi ọ̀pọ̀tọ́ ṣe nípa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì? (Máàkù 11:12-14, 20, 21) [w03-YR 5/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 2 àti 3]
13. Kí ni ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì lò nígbà tó sọ fún Màríà pé yóò ‘lóyún’ nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bá bà lé e tí agbára Ọlọ́run sì ṣíji bò ó fi hàn? (Lúùkù 1:30, 31, 34, 35) [w08-YR 3/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Lúùkù”; w02-YR 3/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 3; tún wo it-2-E ojú ìwé 56 ìpínrọ̀ 2]
14. Ṣé lóòótọ́ làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń ṣe “ohun tí kò bófin mu ní sábáàtì”? (Lúùkù 6:1, 2) [gt-YR 31]
15. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìmọ̀ràn tí Jésù fún Màtá? (Lúùkù 10:40-42) [w99-YR 9/1 ojú ìwé 31]