Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù June: Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku-Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun-Ṣé O Ti Rí I? àti “Sáwo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọ́ tẹ́ ẹ kọ́kọ́ bá onílé sọ̀rọ̀. Tí onílé bá sì ti ní ìwé yìí, ẹ fi bí wọ́n ṣe lè jàǹfààní látinú rẹ̀ hàn wọ́n nípa jíjẹ́ kí wọ́n mọ bá a ṣe ń fi ìwé náà bá àwọn èèyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Níwọ̀n bí oṣù August ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Kí ẹnì kan tí alága àwọn alábòójútó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ láwọn oṣù March, April, àti May. Bó bá ti parí àyẹ̀wò náà, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó lóṣù tó ń bọ̀.—Ẹ wo ìwé tó ṣàlàyé nípa bó ṣe yẹ ká bójú tó àkáǹtì ìjọ, ìyẹn Instructions for Congregation Accounting (S-27).
◼ A dábàá pé kẹ́ ẹ máa fi àwọn ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán, lóṣù kan ṣáájú déètì tí akéde náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀. Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn fọ́ọ̀mù náà pé pérépéré. Báwọn tó fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà ò bá lè rántí ọjọ́ tí wọ́n ṣèrìbọmi, kí wọ́n fojú bu déètì kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ síbì kan. Kí akọ̀wé kọ déètì náà sórí káàdì Congregation’s Publisher Record (S-21), ìyẹn àkọsílẹ̀ akéde ìjọ.
◼ Láti January 2008 la ti ń kó àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! aláfetígbọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Sípáníìṣì sórí ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.jw.org. Ó tẹ́ ọ̀pọ̀ lọ́rùn láti lọ máa wa àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí jáde látinú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì torí wọ́n máa ń tètè rí ìyẹn ṣe kí àwo pẹlẹbẹ MP3 tí wọ́n béèrè fún nípasẹ̀ ìjọ tó tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Nígbàkigbà táwọn èèyàn bá wa àwọn ìwé ìròyìn jáde báyìí, àwọn àjọ tó pèsè ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń bu owó lé wa. Àmọ́, wíwa àwọn ìwé ìròyìn jáde látinú Íńtánẹ́ẹ̀tì kì í ná wa lówó tó ká máa ṣe àwo MP3 ká sì máa kó o ránṣẹ́ sáwọn ìjọ. Nítorí náà, a rọ àwọn akéde tó máa ń wa àwọn ìwé ìròyìn yìí jáde látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì pé kí wọ́n lọ fagi lé ètò ti wọ́n ṣe láti máa gba àwo MP3 nípasẹ̀ ìjọ. A máa tó fàwọn èdè míì kún àwọn ìwé ìròyìn aláfetígbọ́ tó wà nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.jw.org.
◼ Ẹ jọ̀wọ́, a fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé a ò ní fìwé pe àwọn èèyàn sí àpéjọ agbègbè wa tọdún 2008. Àmọ́, a ti ń ṣètò ìkéde tó máa kárí ayé lọ́nà tó ṣàrà-ọ̀tọ̀ lọ́jọ́ iwájú. A máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ bá a ṣe máa ṣe é nígbà tó bá yá.
◼ Ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ti rí i nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù April 2008 pé October 3 sí 5 la sọ pé àpéjọ àgbègbè máa bẹ̀rẹ̀ ní Uyó, a sì sọ pé ó máa bẹ̀rẹ̀ ní Bàdágìrì ní October 10 sí 12 . Àmọ́ ní báyìí, September 26 sí 28 ni àpéjọ àgbègbè máa bẹ̀rẹ̀ ní Bàdágìrì àti Uyó.