Àwọn Àpéjọ Àgbáyé Ń Fògo fún Jèhófà
1. Kí nìdí tá a fi máa ń ṣe àwọn àpéjọ lọ́dọọdún?
1 Àwọn àpéjọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe lọ́dọọdún máa ń tù wá lára nípa tẹ̀mí, ó máa ń fún wa níṣìírí, ó sì máa ń fún wa láǹfààní láti ní ìfararora tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Àwọn àpéjọ ńlá táwa èèyàn Jèhófà máa ń ṣe tún jẹ́ ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ tá a gbà ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀ tá a sì ń kéde ìhìn rere Ìjọba rẹ̀ fáráyé.
2. Àǹfààní wo ló wà nínú àwọn àpéjọ àgbáyé tá a máa ń ṣe?
2 Ọdọọdún la máa ń ṣe àpéjọ àgbègbè kárí ayé fún àǹfààní gbogbo àwọn ará. Nígbà míì sì rèé, a máa ń ṣe àwọn àpéjọ àgbáyé láwọn ilẹ̀ kan. Irú àwọn àpéjọ báyìí la máa fi ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹgbẹ́ ará tó wà kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì máa ń firú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ jẹ́rìí lọ́nà tó túbọ̀ lágbára.
3. (a) Ṣé gbogbo àwọn tó bá forúkọ sílẹ̀ ló máa lè lọ sí àpéjọ àgbáyé? Ṣàlàyé. (b) Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 14:40 sílò tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ò bá yàn wá pé ka lọ?
3 Bá A Ṣe Máa Ń Yan Àwọn Aṣojú: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ló ti lọ sáwọn àpéjọ àgbáyé rí. Bó pẹ́ bó yá, ó ṣì lè ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn ará láti lọ sí ọ̀kan lára àwọn àpéjọ wọ̀nyí. Àmọ́, káwọn àpéjọ àgbáyé lè lọ bó ti yẹ, kí nǹkan sì lè ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó bójú mu, ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ̀ọ̀kan ló máa ń yan iye àwọn aṣojú tó máa lọ sí àpéjọ àgbáyé kan pàtó. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè ṣojú fún ẹgbẹ́ ará kárí ayé lọ́nà tó bójú mu, kí wọ́n lè fún àwọn ará tó gbà wọ́n lálejò níṣìírí, kí wọ́n sì lè jẹ́rìí fún gbogbo àwọn tó bá ń wò wọ́n. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, gbogbo àwọn tó bá forúkọ sílẹ̀ tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ìjọ wọn sì fọwọ́ sí pé kí wọ́n lọ kọ́ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì lè yàn gẹ́gẹ́ bí aṣojú. Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀ka ọ́fíìsì má yan àwọn kan láti lọ, àmọ́ a gbà pé gbogbo wa pátá ni ìdí pàtàkì tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀ yé.—1 Kọ́r. 14:40.
4. Ta ló ń pinnu iye àwọn aṣojú tó máa lọ sí àpéjọ àgbáyé, kí sì nìdí?
4 Ká bàa lè jẹ́rìí fáwọn èèyàn lọ́nà tó múná dóko, á dáa tí gbogbo wa bá lè kọ́wọ́ ti ètò tó wà nílẹ̀ fún àpéjọ àgbáyé yìí lẹ́yìn. Ìṣòro ló máa dá sílẹ̀ táwọn ará tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ò yàn gẹ́gẹ́ bí aṣojú bá lọ ṣètò tara wọn láti lọ sí àpéjọ àgbáyé. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè tó láǹfààní láti rán àwọn aṣojú lọ sí àpéjọ àgbáyé kan, ló máa pinnu iye àwọn ará tó máa lọ. Èyí sì ṣe pàtàkì kérò má lọ pọ̀ jù níbi tí àpéjọ náà ti máa wáyé. Torí térò bá lọ pọ̀ jù níbi tá a máa lò, ìyẹn ò ní jẹ́ kí àpéjọ náà lọ bó ṣe yẹ, èyí ò sì ní pọ́n wa lé lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ìlú náà.
5. (a) Nǹkan tó kù díẹ̀ káàtó wo la kíyè sí nígbà Àpéjọ Àgbáyé ọdún 2003? (b) Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ló máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti fara mọ́ àwọn ìtọ́ni ètò Ọlọ́run lórí ọ̀ràn yìí?
5 A kíyè sí pé lọ́dún 2003, àwọn aṣojú kan láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó lọ sí àpéjọ àgbáyé nílùú Gánà mú àwọn ọmọ wọn kéékèèké dání láìka gbogbo ohun tí ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ sí pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Kàyéfì ńlá ló jẹ́ fáwọn ará wa tó wá sí àpéjọ àgbáyé náà láti àwọn orílẹ̀-èdè míì torí wọn ò rí ìdí tí ètò Ọlọ́run fi gbà káwọn kan mú àwọn ọmọ kékeré dání. (Wo Hébérù 13:17.) A rọ̀ wá pé ká jọ̀wọ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lórí ọ̀ràn yìí, káwọn àpéjọ àgbáyé wa lè lọ létòletò. Tá a bá fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn arákùnrin wa, ìyẹn á fi kún ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa, á sì fi hàn pé à ń ti ètò Ọlọ́run lẹ́yìn.—1 Kọ́r. 16:16; Fílí. 2:1-4.
6, 7. Kí ló yẹ káwọn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá yàn láti lọ sí àpéjọ àgbáyé fi sọ́kàn?
6 Káwọn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá yàn láti lọ sí àpéjọ àgbáyé fi sọ́kàn pé ìdí táwọn fi ń lọ ṣe àpéjọ yìí ni láti kéde Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó gbòòrò. A máa lè ṣe èyí láṣeyọrí táwọn tá a yàn láti lọ bá kọ́wọ́ ti ètò tó wà fún ìrìn àjò àtàwọn nǹkan míì tí ètò Ọlọ́run ti ṣe, tí wọn ò sì gbẹ̀yìn lọ ṣètò láti lọ sáwọn àpéjọ wọ̀nyí fúnra wọn.
7 Onírúurú ilẹ̀ kárí ayé la ti máa ṣe àpéjọ àgbáyé lọ́dún 2009. Ìlú Gánà ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti máa lọ ṣe àpéjọ àgbáyé tiwọn. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ń yan àwọn aṣojú tó máa lọ sí àpéjọ yìí. Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kọ̀ọ̀kan ti fọwọ́ síwèé ìforúkọsílẹ̀ àwọn akéde, tó ti yara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì ti ṣèrìbọmi, tó wà nínú àwọn ìjọ wọn, wọ́n sì ti fi ránṣẹ́ sí wa. Ohun tá à ń retí lọ́dọ̀ àwọn tá a yàn láti lọ ni pé, káwọn àti àwọn ará wa tó máa wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì sapá láti jẹ́rìí lọ́nà tó múná dóko.
8. Bóyá orílẹ̀ èdè wa la ti fẹ́ ṣe àpéjọ àgbègbè tàbí a máa lọ sí àpéjọ àgbáyé, báwo ló ṣe yẹ ká máa hùwà?
8 Bóyá ẹ̀ka ọ́fíìsì yàn wá láti lọ sí àpéjọ àgbáyé tàbí kó jẹ́ pé orílẹ̀-èdè wa la ti máa ṣe àpéjọ àgbègbè, ẹ jẹ́ ká jẹ́ kí ìwà wa ojoojúmọ́ máa fi hàn pé tọkàntọkàn la fi ń bọlá fún Jèhófà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe!—1 Kọ́r. 10:31; 1 Pét. 2:12.