ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/08 ojú ìwé 3
  • “Tẹ̀ Lé Àwọn Ìṣísẹ̀ Rẹ̀ Pẹ́kípẹ́kí”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Tẹ̀ Lé Àwọn Ìṣísẹ̀ Rẹ̀ Pẹ́kípẹ́kí”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 9/08 ojú ìwé 3

“Tẹ̀ Lé Àwọn Ìṣísẹ̀ Rẹ̀ Pẹ́kípẹ́kí”

1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

1 Jésù ò lọ sí iléèwé àwọn rábì, síbẹ̀ òun ni Òjíṣẹ́ tó já fáfá jù lọ nínú ìtàn. A dúpẹ́ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù wà lákọọ́lẹ̀ fún àǹfààní wa. Ká bàa lè já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a gbọ́dọ̀ “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 Pét. 2:21.

2. Kí ló máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn?

2 Fi Hàn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn: Ìfẹ́ tí Jésù ní fáwọn èèyàn ló mú kó gba tiwọn rò. (Máàkù 6:30-34) Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ló wà “nínú ìrora,” tí wọ́n sì nílò òtítọ́ lójú méjèèjì. (Róòmù 8:22) Tá a bá ń ronú lórí bí nǹkan ò ṣe fara rọ fún wọn, àti bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa bá a nìṣó láti tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. (2 Pét. 3:9) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn á túbọ̀ fẹ́ láti fetí sí ìwàásù wa tí wọ́n bá rí i pé lóòótọ́ la bìkítà nípa wọn.

3. Àwọn ìgbà wo ni Jésù wàásù fáwọn èèyàn?

3 Lo Gbogbo Àǹfààní Tó O Bá Ní Láti Wàásù: Jésù lo gbogbo àǹfààní tó ní láti wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. (Mát. 4:23; 9:9; Jòh. 4:7-10) Àwa náà fẹ́ rí i dájú pé a gbára dì láti wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá a ti ń lọ́wọ́ sáwọn ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́. Àwọn kan máa ń mú Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ dání kí wọ́n bàa lè wàásù níbi iṣẹ́, níléèwé, bí wọ́n bá ń rìnrìn àjò, lọ́jà àti láwọn ibòmíì.

4. Báwo la ṣe lè fi Ìjọba Ọlọ́run ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù wa?

4 Ìjọba Ọlọ́run Ni Kọ́rọ̀ Rẹ Máa Dá Lé: Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù Jésù. (Lúùkù 4:43) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa lè máà dá lé Ìjọba Ọlọ́run ní tààràtà, síbẹ̀ a máa ń rí i dájú pé a jẹ́ káwọn onílé mọ bí Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó. Tá a bá tiẹ̀ mẹ́nu ba àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú inú ayé tó fi hàn pé àkókò òpin là ń gbé, síbẹ̀ “ìhìn rere àwọn ohun rere” ni olórí ohun tá à ń wàásù.—Róòmù 10:15.

5. Kí iṣẹ́ ìwàásù wa tó lè múná dóko, ipa wo ni Bíbélì máa kó?

5 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ni Kó O Máa Lò: Ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi wàásù, Ìwé Mímọ́ ló fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Kò fìgbà kankan kọ́ àwọn èèyàn lérò tara rẹ̀. (Jòh. 7:16, 18) Ó kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀, ó sì fi gbara ẹ̀ lọ́wọ́ àtakò Sátánì. (Mát. 4:1-4) Ká bàa lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó múná dóko, a gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ ká sì máa fohun tá à ń kọ́ ṣèwà hù. (Róòmù 2:21) Nígbà tá a bá ń dáhùn àwọn ìbéèrè lóde ẹ̀rí, a gbọ́dọ̀ máa fi Ìwé Mímọ́ ti ọ̀rọ̀ wa lẹ́yìn, ká sì rí i pé a ka ọ̀rọ̀ náà jáde látinú Bíbélì nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe bẹ́ẹ̀. A fẹ́ káwọn tá à ń wàásù fún rí i pé èrò Ọlọ́run la gbé ohun tá à ń sọ kà, kì í ṣe èrò tara wa.

6. Kí ni Jésù ṣe kọ́rọ̀ rẹ̀ bàa lè wọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́kàn?

6 Jẹ́ Kọ́rọ̀ Rẹ Máa Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” (Jòh. 7:46) Ohun táwọn ọmọ ogun kan sọ nípa Jésù nìyẹn nígbà táwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí béèrè ìdí tí wọ́n fi kọ̀ láti fàṣẹ ọba mú Jésù. Dípò kí Jésù kàn máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí fáwọn olùgbọ́ rẹ̀, ńṣe ló máa ń kọ́ wọn lọ́nà tí ohun tó ń sọ á fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Lúùkù 24:32) Ó fàwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn lójoojúmọ́ ṣàpèjúwe, kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè yé àwọn olùgbọ́ rẹ̀. (Mát. 13:34) Kì í rọ̀jò ọ̀rọ̀ lé àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lórí. (Jòh. 16:12) Jèhófà ni Jésù máa ń pàfiyèsí àwọn èèyàn sí, kì í ṣe ara rẹ̀. Àwa náà lè di olùkọ́ rere bíi ti Jésù, kìkì tá a bá ń ‘fiyè sí ẹ̀kọ́ wa nígbà gbogbo.’—1 Tím. 4:16.

7. Kí nìdí tí Jésù ò fi dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?

7 Má Dẹwọ́ Báwọn Èèyàn Ò Tiẹ̀ Fẹ́ Gbọ́ Tí Wọ́n sì Ń Ṣàtakò: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fetí sí i. (Lúùkù 10:13) Àwọn ará ilé Jésù pàápàá rò pé “orí rẹ̀ ti yí.” (Máàkù 3:21) Láìka gbogbo èyí sí, Jésù ò dẹwọ́. Ó lẹ́mìí pé nǹkan ṣì máa dáa torí ó dá a lójú pé òtítọ́ tó lè sọ àwọn èèyàn dòmìnira lòun ń kéde fáráyé. (Jòh. 8:32) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwa náà ti pinnu pé a ò ní dẹwọ́.—2 Kọ́r. 4:1.

8, 9. Bíi ti Jésù, báwo la ṣe lè yááfì àwọn nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì nítorí ìhìn rere?

8 Yááfì Àwọn Nǹkan Tí Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Ṣe Pàtàkì Kó O Lè Wàásù Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́: Jésù yááfì àwọn nǹkan tara nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Mát. 8:20) Ó máa ń wàásù fún àkókò gígùn, láwọn ìgbà míì pàápàá, ó máa ń wàásù títí dalẹ́. (Máàkù 6:35, 36) Jésù mọ̀ pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló kù fóun láti parí iṣẹ́ náà. Níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù,” ó yẹ ká fara wé Jésù, káwa náà lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù náà lẹ́yìn.—1 Kọ́r. 7:29-31.

9 Òjíṣẹ́ tó já fáfá làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní torí pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù. (Ìṣe 4:13) Àwa náà lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tá a bá fara wé Òjíṣẹ́ tó já fáfá jù lọ nínú ìtàn.—2 Tím. 4:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́