Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Ẹ̀yin Ará Wa Olùfẹ́ Ọ̀wọ́n Tá A Jọ Jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà:
Inú wa dùn gan-an láti kọ ìwé yìí sí ẹ̀yin ará wa ọ̀wọ́n! Bíi ti àpọ́sítélì Jòhánù ló ṣe rí lára wa, ẹni tó sọ pé òun ‘nífẹ̀ẹ́ tòótọ́’ sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ òun àti pé inú òun dùn pé wọ́n “ń rìn nínú òtítọ́.” (2 Jòh. 1, 4) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa pé a mọ òtítọ́! Òtítọ́ ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú ìdè Bábílónì Ńlá àti lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run. Ìgbọ́ràn sí Ọlọ́run ti sọ wá di onífẹ̀ẹ́, onínúure àti aláàánú èèyàn. Mímọ̀ tá a mọ òtítọ́ sì ti sọ wá dẹni tó wà ní ipò mímọ́ lójú Ọlọ́run a sì tún nírètí ìyè àìnípẹ̀kun.
Bákan náà, à ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀mí rẹ̀ tó ń darí wa lójoojúmọ́ tó sì ń fún wa lókun! Ó dá wa lójú pé ẹ ti gbádùn oríṣiríṣi ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi ẹ̀mí rẹ̀ darí wa ní Àpéjọ Àgbègbè tá a ṣe láìpẹ́ yìí, ìyẹn Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Wa.” Bí ipò nǹkan ti ń burú sí i nínú ayé, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká gbẹ́kẹ̀ lé ẹ̀mí Jèhófà láti darí wa la àwọn àkókò líle koko tó ń bọ̀ yìí já.
Ó dá wa lójú pé, ó ń wọ̀ yín lọ́kàn gan-an bẹ́ ẹ ṣe ń ka àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wúni lórí nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook nípa báwọn arákùnrin wa ṣe fara da ọ̀pọ̀ ìjìyà nítorí ìgbàgbọ́. Ohun tó wúni lórí jù ni pé kò pẹ́ tí púpọ̀ lára àwọn olóòótọ́ yìí ṣèrìbọmi tí ìṣòro fi dé, a tiẹ̀ rí àwọn tí kò tí ì ṣèrìbọmi nínú wọn. A mà nífẹ̀ẹ́ wọn o, fún ìdúróṣinṣin àti ìṣòtítọ́ wọn! Ká sòótọ́, àpẹẹrẹ rere wọn ti jẹ́ kí ìpinnu tá a ṣe lágbára sí i, pé a ó máa bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run láìka ìṣòro yòówù kó yọjú sí.—1 Tẹs. 1:6-8.
Ẹ̀yin ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, a mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro lẹ̀ ń dojú kọ lórí ọ̀rọ̀ àtijẹ àtimu àtàwọn nǹkan mí ì láti lè mú kí ìfẹ́ so yín pọ̀ nínú ìdílé yín. Ọ̀pọ̀ nínú yín ni kò sì rọrùn fún láti máa fi taratara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìgbòkègbodò mí ì nínú ìjọ déédéé. Ìdí nìyí tá a fi ṣe àwọn àyípadà kan nínú àkókò tá a fi ń ṣe ìpàdé ìjọ bẹ̀rẹ̀ láti January 1, 2009, lẹ́yìn tá a ti gbé e yẹ̀ wò tàdúrà-tàdúrà. A gbà gbọ́ pé ẹ máa lo àǹfààní yìí dáadáa fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé.
Ayọ̀ wa kún bá a ṣe rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó tóótun láti ṣèrìbọmi láwọn àpéjọ àyíká, àkànṣe àti àgbègbè tá a ṣe lọ́dún tó kọjá. Àwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn ṣì kéré wà lára àwọn tó ṣèrìbọmi. A gbóríyìn fún ẹ̀yin òbí fún bẹ́ ẹ ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ yín láti mọyì òtítọ́ àti bẹ́ ẹ ṣe ń fún wọn níṣìírí láti ya ara wọn sí mímọ́ láti sin Jèhófà nígbà ọ̀dọ́. Pẹ̀lú báwọn ọ̀dọ́ olùfẹ́ ọ̀wọ́n yìí ṣe máa ń kojú àwọn ìṣòro nílé ìwé, síbẹ̀ tí wọ́n ṣì tóótun láti ṣèrìbọmi ti jẹ́ ká rí ipa tẹ́yin òbí ń sà láti kọ́ wọn láti ilé.—Sm. 128: 1-6.
Ohun mí ì tá ò tún lè ṣaláì mẹ́nu bà ni bí iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń darí ṣe lọ sókè sí i. Àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe wa tó ń ṣiṣẹ́ kára kópa pàtàkì nínú èyí. Gbogbo àwa tá a wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọyì ipa tẹ́yin arákùnrin àti arábìnrin ń kó nínú sísọ fún gbogbo èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ pé ẹ “Máa bọ̀!” tẹ́ ẹ sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ké sí àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ́ pé kí wọ́n wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣí. 22:17) Tayọ̀tayọ̀ la fi kí gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárùn-ún àti ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀ta ó dín méjì [289,678] to fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi lọ́dún tó kọjá káàbọ̀ sínú ẹgbẹ́ àwọn ará jákèjádò ayé!
Á dáa ká máa rántí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòh. 2:17) Ẹ má sì gbàgbé pé a ti túbọ̀ ń sún mọ́ àkókò táyé yìí máa “kọjá lọ”! Ẹ ò rí i pé ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ báyìí pé ká gbé ìgbésí ayé wa karí ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run, ká sì “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà”. (Mát. 24:42) Ó dájú pé a ò ní kábàámọ̀ láé pé a ṣe bẹ́ẹ̀, a ó sì jàǹfààní inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà.—Aísá. 63:7.
A retí pé àwọn ìròyìn amóríyá láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó wà nínú ìwé ọdọọdún ti ọdún yìí máa jẹ́ ìṣírí fún gbogbo wa láti fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. A fẹ́ kó dá yín lójú pé gbogbo ìgbà là ń rántí yín tá a sì ń gbàdúrà fún yín, àti pé a nífẹ̀ẹ́ yín gan-an ni. Ǹjẹ́ kí Jèhófà máa rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí yín.
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà