Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Àwọn akéde láti ìjọ kan ní ìlú Èkó lọ wàásù ní abúlé Ala àti Idowa ní ìpínlẹ̀ Ogun. Àwọn abúlé náà jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kò yàn fúnni. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn sì so èso rere. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n bá obìnrin kan pàdé níbẹ̀ tó ní àrùn rọpárọsẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ka ìlérí tó wà nínú Bíbélì fún obìnrin náà pé àwọn arọ ṣì máa fi ẹsẹ̀ wọn rìn, obìnrin náà sọ pé: ‘Láti ìgbà tí àìsàn yìí ti ń bá mi fínra, mi ò tíì gbọ́ ọ̀rọ̀ tó tù mí nínú tó báyìí. Mo gba ìlérí yìí gbọ́. Àmọ́, nígbà tẹ́ ẹ ti wá ń lọ báyìí, tí ẹ kò sì ní ilé ìpàdé ní ìlú yìí, ta ni yóò máa kọ́ mi? Ta ni yóò máa tù mí nínú? Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má lọ, ẹ má fi mí sílẹ̀.’ Ṣé ìwọ náà máa lè ṣètò ara rẹ kó o lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́?