Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Lóṣù July ọdún 2010, àwọn akéde tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dógún àti òjìlérúgba ó lé mẹ́sàn-án [303,249] ló ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2010 tá a ní àwọn àkéde tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Iye yìí fi nǹkan bí ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún ju ti oṣù July ọdún 2009. Lóṣù July ọdún 2009, iye àwọn aṣáájú ọ̀nà pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, wọ́n jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti okòó lé lẹ́gbẹ̀ta ó dín ẹyọ kan [30,619], ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹgbẹ̀fà àti mẹ́rìnlélógún [632,024].