Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn láti mọ̀ pé àwọn akéde tó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gọ́ta àti ọ̀tàlénírínwó ó dín mẹ́rin [65,456], ló ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April, 2011. Láfikún sí èyí, àwọn tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé lóṣù yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó dín méjìlá [31,488], àwọn tó sì ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́wàá [810]. Pẹ̀lú èyí, a rí i pé ìdá méjìlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn akéde ló ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Èyí mà wúni lórí gan-an ni o! Èyí fi hàn pé Jèhófà ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀, bí wọ́n ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bí irú èyí tó wà nínú Aísáyà 12:3-5.