Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn 2011 tó kọjá yìí, iye àwọn tó ròyìn ní oṣù July ló tíì pọ̀ ju lọ. Àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàléláàádọ́jọ ó lé ẹgbẹ̀rin àti mẹ́tàdínlógún [306,817] ló ròyìn ní oṣù náà. Ìyẹn ti wá mú kí iye àwọn akéde tó ń ròyìn lóṣooṣù jẹ́ ọ̀kẹ́ márùndínlógún ó lé ọgbọ̀n lé légbèje [301,430], èyí sì fi ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó dín mẹ́rìndínláàádọ́ta [2,954] ju iye àwọn akéde tó ròyìn lóṣooṣù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2010 tó kọjá lọ.