Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ yín ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn ìpàdé míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan. Bí onílé bá ti ní ìwé náà, tí kò sì fẹ́ kí á wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ lè fún un ní àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí onílé nífẹ̀ẹ́ sí. July àti August: Ẹ lo ọ̀kan lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú-ewé 32 wọ̀nyí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, àti Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! kẹ́ ẹ́ sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí.
◼ Ní Friday, May 25, ọdún 2012, kò ní sáyè fún wa láti gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kẹ́ ẹ má ṣe wá gba ìwé lọ́jọ́ yìí.