Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa wúlò fún un jù lọ nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. Kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. May àti June: Ẹ lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tẹ́ ẹ bá ní lọ́wọ́. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ẹ fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. Kí ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. July: Ìwe Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! tàbí èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n yìí: Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. Tẹ́ ẹ bá pàdé ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, kí ẹ fún un ní ìwé Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀ tàbí Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Ló Máa Ṣamọ̀nà Ẹ̀dá Wọ Párádísè.
◼ Nígbàkigbà tó o bá ń ṣètò láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tó o sì fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, o lè rí ìsọfúnni tó o nílò lórí ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org, ní ìlujá tá a pè ní “Àpéjọ Àgbègbè” èyí tó wà lábẹ́ abala “Nípa Wa.”
◼ Lọ́jọ́ Friday, May 24, 2013, kò ní sáyè fún wa láti gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kẹ́ ẹ má ṣe wá gba ìwé lọ́jọ́ náà.