Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 26, 2013. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan síwájú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
1. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ lára Hẹ́rọ́dù Ọba tó gba ìyìn àti ògo látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn? (Ìṣe 12:21-23) [July 1, w08 5/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 7]
2. Àǹfààní wo ló wà nínú kí àwọn ọ̀dọ́ fara balẹ̀ ronú lórí àpẹẹrẹ Tímótì, kí wọ́n sì tẹ̀ lé e? (Ìṣe 16:1, 2) [July 8, w08 5/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 10]
3. Lẹ́yìn tí Àpólò “fi ìgboyà sọ̀rọ̀” nínú sínágọ́gù tó wà ní Éfésù, báwo ni Ákúílà àti Pírísílà ṣe ràn án lọ́wọ́? (Ìṣe 18:24-26) [July 15, w10 6/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 4]
4. Àpẹẹrẹ wo nínú Bíbélì ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé tá a fi máa ń gbé ẹjọ́ lọ sí kóòtù láti gbèjà ẹ̀tọ́ wa láti máa wàásù? (Ìṣe 25:10-12) [July 22, bt ojú ìwé 198 ìpínrọ̀ 6]
5. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe wàásù nígbà tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Róòmù? Báwo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lónìí? (Ìṣe 28:17, 23, 30, 31) [July 29, bt ojú ìwé 216 ìpínrọ̀ 19 sí 23]
6. Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ lòdì sí ìwà ẹ̀dá àti pé ó jẹ́ ohun ìbàjẹ́? (Róòmù 1:26, 27) [Aug. 5, g 4/12 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 7]
7. Báwo ni “ìràpadà tí Kristi Jésù san” lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni ṣe kan “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wáyé ní ìgbà tí ó ti kọjá” kí wọ́n tó san ìràpadà náà? (Róòmù 3:24, 25) [Aug. 5, w08 6/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 6]
8. Tí ìṣòro wa bá pọ̀ débi pé a ò tiẹ̀ mọ ohun tá a lè gbàdúrà lé lórí, ìrànlọ́wọ́ wo ni Jèhófà ti pèsè fún wa? (Róòmù 8:26, 27) [Aug. 12, w08 6/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 10]
9. Kí ni ìtúmọ̀ ohun tí Bíbélì sọ pé, “ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò”? (Róòmù 12:13) [Aug. 19, w09 10/15 ojú ìwé 5 àti 6, ìpínrọ̀ 12 àti 13]
10. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé ká “gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀”? (Róòmù 13:14) [Aug. 26, w05 1/1 ojú ìwé 11 àti 12, ìpínrọ̀ 20 sí 22]