Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní January: A máa pín Ìròyìn Ìjọba No. 38 lákànṣe, àkòrí rẹ̀ ni, Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ti Kú Lè Jíǹde? Tí ẹ bá ti pín gbogbo Ìròyìn Ìjọba tẹ́ ẹ ní lọ́wọ́ tán kí oṣù tó parí, àwọn akéde lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ìwé tá a kọ sí ìsàlẹ̀ yìí fún oṣù tó ń bọ̀. February: Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? tàbí ìwé olójú ewé 32 èyíkéyìí tó bá wà lọ́wọ́. Ẹ lè fún àwọn Mùsùlùmí ní: Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀ tàbí Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Ló Máa Ṣamọ̀nà Ẹ̀dá Wọ Párádísè. March àti April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
◼ Inú wa dùn láti sọ fún yín pé lọ́dún 2014, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí: Badagry ní March 15-16 àti July 6; Benin City ní February 15 àti May 3-4; Ibadan ní June 14-15 àti August 23; Kwali ní May 24-25 àti August 9; Lekki ní March 1-2 àti July 13; Uli ní February 23 àti May 10-11. Bákan náà, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe lédè Faransé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí: Lekki ní April 5-6 àti July 19. Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà àti Èdè Faransé la máa fi ṣe àwọn àpéjọ yìí látòkèdélẹ̀. A ké sí gbogbo àwọn tó gbọ́ àwọn èdè yìí pé kí wọ́n wá.