Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 27, 2015. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
Irú ìfẹ́ wo ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, àwọn apá wo nígbèésí ayé wa ló sì ti wúlò jù lọ? (Rúùtù 1:16, 17) [Mar. 2, ia ojú ìwé 38 ìpínrọ̀ 19]
Kí ló mú káwọn èèyàn mọ Rúùtù sí “obìnrin títayọ lọ́lá”? (Rúùtù 3:11) [Mar. 2, ia ojú ìwé 48 ìpínrọ̀ 21]
Tá a bá wà nínú ìṣòro, kí la lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hánà? (1 Sám. 1:16-18) [Mar. 9, w07 3/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 4 àti 5]
Nígbà tí Sámúẹ́lì wà lọ́mọdé, tó ń ‘dàgbà lọ́dọ̀ Jèhófà,’ kí ni kò jẹ́ kí ìwà ìbàjẹ́ àwọn ọmọ Élì nípa lórí rẹ̀? (1 Sám. 2:21) [Mar. 9, ia ojú ìwé 63 ìpínrọ̀ 16 àti 17]
Kí la lè rí kọ́ nínú bí Sọ́ọ̀lù ò ṣe ṣìwà hù nígbà tí àwọn kan tó jẹ́ “ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun” ò gbà pé kó jọba lé àwọn lórí? (1 Sám. 10:22, 27) [Mar. 23, w05 3/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 2]
Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú bí Sọ́ọ̀lù ṣe ní èrò tí kò tọ̀nà pé òun lè fi ẹbọ rírú rọ́pò ṣíṣe ìgbọràn sí Jèhófà? (1 Sám. 15:22, 23) [Mar. 30, w07 6/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
Kí nìdí tó fi jẹ́ ohun tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa ń wo “ohun tí ọkàn àyà jẹ́”? (1 Sám. 16:7) [Apr. 6, w10 3/1 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 7]
Ní ìbámu pẹ̀lú Òwe 1:4, kí làwọn ohun tí Jèhófà fún wa tó ń retí pé ká lò tá a bá wa nínú ìṣòro líle koko? (1 Sám. 21:12, 13) [Apr. 13, w05 3/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 5]
Kí nìdí tí ohun tí Ábígẹ́lì ṣe kò fi túmọ̀ sí pé ó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọkọ tó jẹ́ orí rẹ̀ nígbà tó fún Dáfídì àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní oríṣiríṣi ẹ̀bùn? (1 Sám. 25:10, 11, 18, 19) [Apr. 20, w09 7/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 4]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábígẹ́lì kọ́ ló ṣẹ Dáfídì àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, síbẹ̀ ó tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ wọn. Kí lèyí kọ́ wa? (1 Sám. 25:24) [Apr. 20, w02 11/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1 àti 4]