ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 July ojú ìwé 2
  • July 4 Sí 10

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July 4 Sí 10
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 July ojú ìwé 2

July 4 Sí 10

SÁÀMÙ 60-68

  • Orin 104 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • “Ẹ Yin Jèhófà, Olùgbọ́ Àdúrà”: (10 min.)

    • Sm 61:1, 8​—Tó o bá ṣèlérí fún Jèhófà, máa bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ (w99 9/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

    • Sm 62:8​—Tó o bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Jèhófà, ìyẹn á fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé e (w15 4/15 ojú ìwé 25 àti 26 ìpínrọ̀ 6 sí 9)

    • Sm 65:1, 2​—Jèhófà ni Olùgbọ́ àdúrà gbogbo àwọn tó lọ́kàn rere (w15 4/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 13 àti 14; w10 4/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 10; it-2 ojú ìwé 668 ìpínrọ̀ 2)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Sm 63:3​—Kí nìdí tí inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà fi sàn ju ìyè? (w06 6/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 7)

    • Sm 68:18​—Àwọn wo ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”? (w06 6/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 5)

    • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

    • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 63:1–64:10

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 81

  • “Jẹ́ Kí Ohun Díẹ̀ Tẹ́ Ọ Lọ́rùn Kó O Lè Túbọ̀ Máa Yin Ọlọ́run”: (15 min.) Ẹ kọ́kọ́ jíròrò àpilẹ̀kọ náà. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní A Jẹ́ Kóhun Díẹ̀ Tẹ́ Wa Lọ́rùn, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀ ní ṣókí. Fídíò yìí wà lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW (Lọ sí WO FÍDÍÒ LÓRÍṢIRÍṢI > ÌDÍLÉ.) Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n wo àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè túbọ̀ máa sin Jèhófà.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 19 ìpínrọ̀ 1 sí 16

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 88 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́