January 2-8
Aísáyà 24-28
Orin 12 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Àwọn Èèyàn Rẹ̀”: (10 min.)
Ais 25:4, 5—Jèhófà jẹ́ ibi ààbò nípa tẹ̀mí fún àwọn tó fẹ́ jọ́sìn rẹ̀ (ip-1 272 ¶5)
Ais 25:6—Jèhófà ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa lọ́pọ̀ yanturu (w16.05 24 ¶4; ip-1 273 ¶6-7)
Ais 25:7, 8—Ọlọ́run máa tó mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kúrò títí láé (w14 9/15 26 ¶15; ip-1 273-274 ¶8-9)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ais 26:15—Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ bí Jèhófà ṣe ń “sún gbogbo ojú ààlà ilẹ̀ náà síwájú”? (w15 7/15 11 ¶18)
Ais 26:20—Kí ló ṣeé ṣe kí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ‘yàrá inú lọ́hùn-ún’ tọ́ka sí? (w13 3/15 23 ¶15-16)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 28:1-13
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Lóṣù January, àwọn ará lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! lóde ẹ̀rí, tí wọ́n bá pàdé ẹni tó fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (15 min.) Ẹ tún lè jíròrò ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb16 140-142)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 6 ¶8-15 àti àpótí “Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Ayé àtijọ́ Tó Ta Àwọn Ará Jí Sí Iṣẹ́ Ìwàásù”
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 66 àti Àdúrà