April 10-16
Jeremáyà 22-24
Orin 52 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ǹjẹ́ O Ní ‘Ọkàn-àyà Láti Mọ’ Jèhófà?”: (10 min.)
Jer 24:1-3—Jèhófà fi àwọn èèyàn wé èso ọ̀pọ̀tọ́ (w13 3/15 8 ¶2)
Jer 24:4-7—Àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ tó dára ṣàpẹẹrẹ àwọn tó fọkàn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn (w13 3/15 8 ¶4)
Jer 24:8-10—Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára ṣàpẹẹrẹ àwọn ọlọ̀tẹ̀, tí ọkàn wọn ti yigbì, tí wọ́n sì jẹ́ aláìgbọràn (w13 3/15 8 ¶3)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jer 22:30—Kí nìdí tí àṣẹ yìí kò fi fagi lé ẹ̀tọ́ tí Jésù ní láti gorí ìtẹ́ Dáfídì? (w07 3/15 10 ¶9)
Jer 23:33—Kí ni “ẹrù ìnira Jèhófà”? (w07 3/15 11 ¶1)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jer 23:25-36
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn g17.2 —Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn g17.2—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) lv 5 ¶1-2—Fi béèyàn ṣe lè dé ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ hàn.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Fún Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Ẹ Máa Fáwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 11 ¶1-8
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 93 àti Àdúrà