ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 July ojú ìwé 4
  • July 16-22

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July 16-22
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 July ojú ìwé 4

July 16-22

Lúùkù 10-11

  • Orin 100 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • “Àpèjúwe Ará Samáríà”: (10 min.)

    • Lk 10:​29-32​—Àlùfáà kan àti ọmọ Léfì kan kọ̀ láti ṣèrànwọ́ fún Júù bíi tiwọn táwọn olè dá lọ́nà [Jẹ́ kí àwọn ará wo “Ọ̀nà Tó Lọ Láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò” àwòrán àti fídíò lórí Lk 10:30, nwtsty] (w02 9/1 16-17 ¶14-15)

    • Lk 10:33-35​—Ará Samáríà kan fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí ẹni táwọn olè dá lọ́nà (“ará Samáríà kan,” “ó sì di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti wáìnì sórí wọn,” “ilé èrò” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 10:33, 34, nwtsty)

    • Lk 10:36, 37​—A gbọ́dọ̀ fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn, kì í ṣe kìkì àwọn tá a jọ wà nípò kan náà, ọmọ ìlú kan náà tàbí tá a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà (w98 7/1 31 ¶2)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Lk 10:18​—Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn àádọ́rin [70] ọmọ ẹ̀yìn náà pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run”? (“Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run”  àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 10:18, nwtsty; w08 3/15 31-32 ¶11)

    • Lk 11:5-9​—Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nípa àdúrà nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọkùnrin tó tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè ohun tó fẹ́? (“Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù búrẹ́dì mẹ́ta,” “Yé dà mí láàmú,” “ìtẹpẹlẹ rẹ̀ aláìṣojo” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 11:5-9, nwtsty;)

    • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lk 10:​1-16

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ẹni náà sọ ohun táwọn kan sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù.

  • Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé òun ń jẹun lọ́wọ́.

  • Ìpadàbẹ̀wò Kejì​—Fídíò: (5 min) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 24

  • “Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Má Dá Sí Ọ̀ràn Òṣèlú? (Mík. 4:2)”: (15 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 10 ¶9-15 àti àpótí ojú ìwé 114

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 146 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́