October 15-21
JÒHÁNÙ 13-14
Orin 100 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Mo Fi Àwòṣe Lélẹ̀ fún Yín”: (10 min.)
Jo 13:5—Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ (“wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 13:5, nwtsty)
Jo 13:12-14—Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ‘wẹ ẹsẹ̀ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì’ (“ó yẹ” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 13:14, nwtsty)
Jo 13:15—Gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù fi lélẹ̀ (w99 3/1 31 ¶1)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Jo 14:6—Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ “ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè”? (“Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 14:6, nwtsty)
Jo 14:12—Báwo ni àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jésù ṣe máa “ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju” ti Jésù? (“àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 14:12, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jo 13:1-17
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ láti wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà.
Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ.
Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ìfẹ́ Ni A Fi Ń Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀—Kọ Ìmọtara-Ẹni-Nìkan àti Ìbínú Sílẹ̀”: (15 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò náà “Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín”—Kọ Ìmọtara-Ẹni-Nìkan àti Ìbínú Sílẹ̀. Bí àkókò bá ṣe wà sí, sọ̀rọ̀ lórí àpótí náà “Ṣàṣàrò Lórí Àpẹẹrẹ Inú Bíbélì.”
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 14 ¶10-14, àpótí Àwọn Irọ́ Tí Sátánì Ń Pa Nípa Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Burú Jáì, àfikún Bá A Ṣe Lè Máa Yanjú Aáwọ̀ Nínú Ọ̀ràn Ìṣòwò
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 120 àti Àdúrà