October 14-20
1 PÉTÉRÙ 1-2
Orin 29 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Pétérù Kìíní.]
1Pe 1:14, 15—Ìfẹ́ ọkàn wa àti ìwà wa gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ (w17.02 9 ¶5)
1Pe 1:16—A gbọ́dọ̀ sapá láti fara wé Jèhófà Ọlọ́run mímọ́ (lv 64-65 ¶6)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
1Pe 1:10-12—Báwo la ṣe lè fara wé àwọn wòlíì àtàwọn áńgẹ́lì? (w08 11/15 21 ¶10)
1Pe 2:25—Ta ni Alábòójútó Gíga Jù Lọ? (it-2 565 ¶3)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 1Pe 1:1-16 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 1)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 3)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Fún un ní ọ̀kan lára ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 9)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Máa Wà ní Mímọ́ Tónítóní: (6 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n pé: Kí ni Jèhófà ṣe kí gbogbo nǹkan lè wà létòlétò? Kí ló ń jẹ́ káwọn erinmi wà ní mímọ́ tónítóní? Kí nìdí tó fi yẹ kó o jẹ́ kí ilé yín máa wà ní mímọ́ tónítóní?
“Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Mímọ́”: (9 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Mímọ́.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 11 ¶12-18
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 39 àti Àdúrà