July 4-10
2 SÁMÚẸ́LÌ 18-19
Orin 138 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Mọ̀wọ̀n Ara Ẹ Bíi Ti Básíláì”: (10 min.)
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.)
2Sa 19:24-30—Kí la rí kọ́ lára Méfíbóṣétì tó lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun? (w20.04 30 ¶19)
Àwọn ìṣúra wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) 2Sa 19:31-43 (th ẹ̀kọ́ 2)
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́ fún Wa—Jẹ 1:28. Ẹ dá fídíò náà dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, kẹ́ ẹ sì dáhùn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ.
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Àkòrí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀.a Ẹni náà sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 1)
Àsọyé: (5 min.) w21.08 23-25 ¶15-19—Àkòrí: Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn Tí Ipò Rẹ Ò Bá Jẹ́ Kó O Lè Ṣe Tó Bó O Ṣe Fẹ́? (th ẹ̀kọ́ 20)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ohun Tó O Lè Fi Ṣe Àfojúsùn ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀—Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ẹ Jẹ́ Onígboyà . . . Ẹ̀yin Aṣáájú-Ọ̀nà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lff ẹ̀kọ́ 11
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 97 àti Àdúrà
a Wo àpilẹ̀kọ tó wà ní ojú ìwé 16.