September 5-11
1 ÀWỌN ỌBA 9–10
Orin 10 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Máa Yin Jèhófà Nítorí Ọgbọ́n Rẹ̀”: (10 min.)
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.)
1Ọb 10:10, 14—Kí ló fi hàn pé ìwọ̀n góòlù tí Bíbélì sọ pé Ọba Sólómọ́nì ní kì í ṣe àsọdùn? (w08 11/1 22 ¶4-6)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) 1Ọb 10:1-13 (th ẹ̀kọ́ 5)
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Nígbà Àkọ́kọ́: Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì—Sm 37:29. Ẹ dá fídíò náà dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, kẹ́ ẹ sì dáhùn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ.
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ fún àkànṣe ìwàásù láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni kó o lò. (th ẹ̀kọ́ 1)
Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min.) Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ fún àkànṣe ìwàásù láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni kó o fi bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀kọ́ 01 nínú ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 13)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Wàá Rí Ìmọ̀ràn Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Lórí Ìkànnì JW.ORG”: (8 min.) Ìjíròrò. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n lọ sórí Ìkànnì jw.org kí wọ́n lè rí ìmọ̀ràn Bíbélì tí wọ́n lè fi yanjú àwọn ìṣòro ojoojúmọ́.
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (7 min.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lff ẹ̀kọ́ 18 kókó 6-7 àti kókó pàtàkì, kí lo rí kọ́, àti ohun tó yẹ kó o ṣe
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 106 àti Àdúrà