ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 January ojú ìwé 3-16
  • January 8-14

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • January 8-14
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 January ojú ìwé 3-16

JANUARY 8-14

JÓÒBÙ 34-35

Orin 30 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Èrò Tó Yẹ Ká Ní Tí Wọ́n Bá Ń Rẹ́ Wa Jẹ

(10 min.)

Máa rántí pé Jèhófà kọ́ ló ń fa ìwà ìrẹ́jẹ (Job 34:10; wp19.1 8 ¶2)

Lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè dà bíi pé àwọn ẹni burúkú mú ìwà ibi wọn jẹ, àmọ́ wọn ò lè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Jèhófà (Job 34:21-26; w17.04 10 ¶5)

Ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà ran àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ lọ́wọ́ ni pé ká kọ́ wọn nípa Jèhófà (Job 35:9, 10; Mt 28:19, 20; w21.05 7 ¶19-20)

Tọkọtaya kan ń wàásù fún ọkùnrin kan àti ọmọ ẹ̀ tó ń gbé níbi táwọn tálákà ń gbé, ilé ńláńlá táwọn olówó kọ́ wà lẹ́yìn.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Job 35:7—Kí ni Élíhù ní lọ́kàn nígbà tó bi Jóòbù pé: ‘Kí ni [Ọlọ́run] gbà lọ́wọ́ rẹ?’ (w17.04 29 ¶3)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Job 35:1-16 (th ẹ̀kọ́ 10)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 10 kókó 3)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi han ẹnì kan tó ní àwọn ọmọ kéékèèké bó ṣe lè rí àwọn ẹ̀kọ́ táwọn òbí lè lò láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lórí ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) lff ẹ̀kọ́ 13 kókó 5 (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 3)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 58

7. Ṣé Ó Máa Ń Wù Ẹ́ Láti “Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà” Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà?

(15 min.) Ìjíròrò.

Arábìnrin kan ń fi fóònù wàásù fún obìnrin kan nínú ọkọ̀ èrò.

Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà; máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìfi falẹ̀.” (2Ti 4:2) Nígbà míì, wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tí wọ́n tú sí “máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìfi falẹ̀” fáwọn ológun láti fi tọ́ka sí sójà tàbí olùṣọ́ kan tó wà níbi tí wọ́n ní kó máa ṣọ́, tó sì wà ní sẹpẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀ nígbàkigbà. Èyí fi hàn pé ó yẹ káwa náà wà ní sẹpẹ́ nígbà gbogbo láti wàásù fún ẹnikẹ́ni tá a bá pàdé níbikíbi.

Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọyì àwọn ohun rere tó ṣe fún wa, ìyẹn máa ń mú kó wù wá láti sọ nípa irú ẹni tó jẹ́ fáwọn míì.

Ka Sáàmù 71:8. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

Àwọn nǹkan rere wo nípa Jèhófà ni wàá fẹ́ sọ fáwọn míì?

A tún ń wàásù fáwọn èèyàn lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Bí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo ni ìwàásù àìjẹ́-bí-àṣà ṣe ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti rí òtítọ́?

  • Báwo ni òtítọ́ tí àwọn tó ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́lẹ̀ kọ́ ṣe ṣe wọ́n láǹfààní?

  • Báwo ni ìfẹ́ tá a ní sáwọn èèyàn ṣe ń jẹ́ kó wù wá láti wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà?

  • Kí nìdí tó o fi gbà pé ìwàásù àìjẹ́-bí-àṣà gbéṣẹ́ gan-an tó bá di pé ká kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 4, àpótí tó wà lójú ìwé 33

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 138 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́