ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 July ojú ìwé 14-15
  • August 26–September 1

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • August 26–September 1
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 July ojú ìwé 14-15

AUGUST 26–SEPTEMBER 1

SÁÀMÙ 78

Orin 97 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwòrán: Ọmọ Ísírẹ́lì kan ń bu mánà sókè. Ó bojú jẹ́ bó ṣe ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn ní Íjíbítì. 1. Ó ń jẹ bàrà olómi. 2. Àwọn ọmọ Íjíbítì ń lu àwọn Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ẹrú, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n.

1. Ìkìlọ̀ Ni Ìwà Àìṣòótọ́ Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Jẹ́ fún Wa

(10 min.)

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàgbé àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí Jèhófà ṣe (Sm 78:11, 42; w96 12/1 29-30)

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà pèsè fún wọn (Sm 78:19; w06 7/15 17 ¶16)

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe wọn, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n sọ ìwà burúkú dàṣà (Sm 78:40, 41, 56, 57; w11 7/1 10 ¶3-4)


RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Kí ni ò ní jẹ́ ká di aláìṣòótọ́ sí Jèhófà?

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 78:24, 25—Kí nìdí tí Bíbélì fi pe mánà ní “ọkà ọ̀run” àti “oúnjẹ àwọn alágbára”? (w06 7/15 11 ¶5)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 78:1-22 (th ẹ̀kọ́ 5)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìléwọ́ wa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 4)

6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(1 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé kó o má jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ gùn jù. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)

7. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Wá ọ̀nà tó o lè gbà jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́ láìjẹ́ pé o mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ Bíbélì, kó o sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 96

8. Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Fílípì Ajíhìnrere

(15 min.) Ìjíròrò.

Fílípì ajíhìnrere ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún ìwẹ̀fà ará Etiópíà nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó ṣe ohun rere àtàwọn tó ṣe búburú ló wà nínú Bíbélì. Ó máa gba àkókò àti ìsapá ká tó lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ yẹn. Yàtọ̀ sí kíka àwọn ìtàn Bíbélì yìí, ó tún yẹ ká ronú lórí ohun tá a kà, ká sì fi àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa.

Àwọn èèyàn mọ Fílípì ajíhìnrere sí Kristẹni tó “kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n.” (Iṣe 6:3, 5) Kí la lè kọ́ lára ẹ̀?

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Wọn—Fílípì Ajíhìnrere. Lẹ́yìn náà, béèrè ohun táwọn ará kọ́ nínú àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí:

  • Kí ni Fílípì ṣe nígbà tí nǹkan yí pa dà fún un?—Iṣe 8:1, 4, 5

  • Àwọn ìbùkún wo ni Fílípì rí torí pé ó lọ sìn níbi tí àìní wà?—Iṣe 8:6-8, 26-31, 34-40

  • Àǹfààní wo ni Fílípì àti ìdílé ẹ̀ rí torí pé wọ́n gba àwọn míì lálejò?—Iṣe 21:8-10

  • Àǹfààní wo ni ìdílé inú fídíò náà rí torí pé wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Fílípì?

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 14 ¶11-20

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 101 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́