ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 September ojú ìwé 4
  • September 9-15

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • September 9-15
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 September ojú ìwé 4

SEPTEMBER 9-15

SÁÀMÙ 82-84

Orin 80 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Kórà ń wo ìtẹ́ ẹyẹ alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tó wà ní àgbàlá tẹ́ńpìlì

1. Mọyì Ohunkóhun Tó O Bá Ń Ṣe Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

(10 min.)

A mọyì iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tá a bá láǹfààní láti ṣe (Sm 84:1-3; wp16.6 8 ¶2-3)

Máa fayọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá ní nínú ètò Ọlọ́run dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá lórí èyí tó wù ẹ́ kó o ní (Sm 84:10; w08 7/15 30 ¶3-4)

Jèhófà máa ń ṣojú rere sí gbogbo àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn (Sm 84:11; w20.01 17 ¶12)

Àwòrán: Àwọn ọmọ Léfì ń ṣe onírúurú iṣẹ́. 1. Ọ̀kan ń da omi látinú ìkòkò sínú bàsíà bàbà. 2. Ọ̀kan ń ti kẹ̀kẹ́ tí ìkòkò kún inú ẹ̀. 3. Ọ̀kan gbé ìkòkò sí èjìká rẹ̀.

Kò sí iṣẹ́ ìsìn tí kò ní ìbùkún àti ìṣòro tiẹ̀. Tó o bá ń ronú nípa àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀, kò sí iṣẹ́ ìsìn tó ò ní gbádùn.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 82:3—Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn “ọmọ aláìníbaba” tó wà nínú ìjọ? (it-1 816)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 82:1–83:18 (th ẹ̀kọ́ 2)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò—Ohun Tí Jésù Ṣe

(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 1-2.

5. Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò—Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

(8 min.) Ìjíròrò tó dá lórí lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3-5 àti “Tún Wo.”

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 57

6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(15 min.)

7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 15 ¶8-12, àpótí ojú ìwé 118

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 130 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́