ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 September ojú ìwé 14-15
  • October 28–November 3

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • October 28–November 3
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 September ojú ìwé 14-15

OCTOBER 28–NOVEMBER 3

SÁÀMÙ 103-104

Orin 30 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. “Ó Rántí Pé Erùpẹ̀ Ni Wá”

(10 min.)

Torí pé aláàánú ni Jèhófà, ó máa ń gba tiwa rò (Sm 103:8; w23.07 21 ¶5)

Kò ní pa wá tì tá a bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe (Sm 103:9, 10; w23.09 6-7 ¶16-18)

Kì í retí ohun tó ju agbára wa lọ (Sm 103:14; w23.05 26 ¶2)

Ọkọ kan ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìyàwó ẹ̀ bó ṣe ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo ọkọ tàbí aya mi lèmi náà fi ń wò ó, ṣé mo sì máa ń gba tiẹ̀ rò?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 104:24—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká rí i pé oníṣẹ́ àrà ni Jèhófà, àti pé agbára rẹ̀ ò láfiwé? (cl 55 ¶18)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 104:1-24 (th ẹ̀kọ́ 11)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jíròrò fídíò Ohun Tó O Máa Gbádùn Nínú Ẹ̀kọ́ Bíbélì Rẹ pẹ̀lú ẹnì kan tó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 9)

6. Àsọyé

(5 min.) lmd àfikún A kókó 6—Àkòrí: Ó Yẹ Kí Ọkọ “Nífẹ̀ẹ́ Aya Rẹ̀ Bó Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ara Rẹ̀.” (th ẹ̀kọ́ 1)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 44

7. Ó Yẹ Ká Mọ Ohun Tágbára Wa Gbé

(15 min.) Ìjíròrò.

Inú Jèhófà máa dùn tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, àwa náà sì máa láyọ̀. (Sm 73:28) Àmọ́, ó yẹ ká mọ ibi tágbára wa mọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́kàn sókè, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá wa.

Arábìnrin kan tó wà ní fídíò “A Máa Tẹ̀ Síwájú Tá A Bá Ń Ronú Nípa Nǹkan Tọ́wọ́ Wa Lè Tẹ̀.”

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ A Máa Tẹ̀ Síwájú Tá A Bá Ń Ronú Nípa Nǹkan Tọ́wọ́ Wa Lè Tẹ̀. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe? (Mik 6:8)

  • Apá kan nínú fídíò “A Máa Tẹ̀ Síwájú Tá A Bá Ń Ronú Nípa Nǹkan Tọ́wọ́ Wa Lè Tẹ̀.” Ọ̀dọ́bìnrin kan àti ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan níṣìírí.
  • Kí ni kò jẹ́ kí arábìnrin náà da ara ẹ̀ láàmú mọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ẹ̀ ò tíì tẹ àfojúsùn ẹ̀?

BÁWO LA ṢE LÈ MỌ OHUN TÁGBÁRA WA GBÉ?

  • Má ṣe máa fi ara ẹ wé àwọn míì. (Ga 6:4) Kò yẹ ká máa wo aago aláago ṣiṣẹ́. Ó ṣeé ṣe kó o lè ṣe ju ẹni tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ẹgbẹ́ tàbí tí ipò yín jọra, ó sì lè má lè ṣe tó ẹni náà

  • Má ṣe ronú pé o ò ní lè ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀. (Ro 12:1; 1Kọ 7:31) Má ṣe jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn kan tó o rò pé o ò ní lè ṣe, tàbí tí kò wù ẹ́ láti ṣe.—Mal 3:10

  • Ní àwọn àfojúsùn tó máa jẹ́ kó o mọ ohun tágbára ẹ gbé. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o wù ẹ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé? O lè fi àwọn àfojúsùn tágbára ẹ gbé bẹ̀rẹ̀ ná. Àbá kan rèé: Fáwọn oṣù mélòó kan, o lè fi kún iye àkókò tó ò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tàbí kó o ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Kódà, o lè gbìyànjú láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé fún ọdún kan. Ká tiẹ̀ wá sọ pé o ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí pé o ò lè ṣe é ju ọdún kan lọ, o ò ní kábàámọ̀ láé pé ọwọ́ ẹ tẹ àwọn àfojúsùn tágbára ẹ gbé.—Onw 6:9

  • Mọ̀ pé nǹkan lè yí pa dà. Bí ipò wa ṣe ń yí pa dà, bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tágbára wa gbé máa ń yí pa dà. Torí náà, máa ṣe àwọn àyípadà tó bá yẹ sí àfojúsùn ẹ látìgbàdégbà

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 17 ¶8-12, àpótí ojú ìwé 137

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 55 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́