ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb25 March ojú ìwé 12-13
  • April 21-27

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • April 21-27
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
mwb25 March ojú ìwé 12-13

APRIL 21-27

ÒWE 10

Orin 76 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Kí Ló Ń Jẹ́ Kéèyàn Ní Ọrọ̀ Tòótọ́?

(10 min.)

Tá a bá ń “ṣiṣẹ́ kára” láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ Jèhófà, àá di ọlọ́rọ̀ lójú Ọlọ́run(Owe 10:4, 5; w01 7/15 25 ¶1-3)

Kéèyàn jẹ́ olódodo ṣe pàtàkì ju kéèyàn kó nǹkan ìní jọ (Owe 10:15, 16; w01 9/15 24 ¶3-4)

Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀ (Owe 10:22; it-1 340)

Àwọn arábìnrin méjì dì mọ́ra ní àpéjọ agbègbè kan.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 10:22—Tó bá jẹ́ pé Jèhófà kì í fi ìrora kún ìbùkún rẹ̀, kí wá nìdí táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi máa ń ní ọ̀pọ̀ ìṣòro? (w06 5/15 30 ¶18)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Owe 10:1-19 (th ẹ̀kọ́ 10)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà sọ pé òun ò gba Ọlọ́run gbọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.(lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 4)

6. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jẹ́ kí ẹni náà rí bó ṣe lè wá ohun tó bá wù ú lórí ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 111

7. Báwo Làwọn Ìbùkún Jèhófà Ṣe Ń Jẹ́ Káwọn Ìránṣẹ́ Ẹ̀ Láyọ̀?

(7 min.) Ìjíròrò.

Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan le yìí, Jèhófà máa ń bù kún àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, ìyẹn ló sì ń jẹ́ ká lè fara dà á ká sì máa láyọ̀. (Sm 4:3; Owe 10:22) Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí. Lẹ́yìn náà, ní káwọn ará sọ bí ìbùkún tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe ń jẹ́ ká láyọ̀.

  • Ais 65:13

  • Lk 11:13

  • Jo 13:35

Àwọn kan ti fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ láyọ̀.

Apá kan nínú fídíò “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Fi Ayé Yín Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Ọkàn Yín Balẹ̀!” 1. Harley. 2. Anjil. 3. Carlee.

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Fi Ayé Yín Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Ọkàn Yín Balẹ̀! Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo rí kọ́ lára Harley, Anjil, àti Carlee?

8. Ìròyìn Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ti Ọdún 2025

(8 min.) Àsọyé. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà.

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 25 ¶8-13, àpótí ojú ìwé 201

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 115 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́