SEPTEMBER 1-7
ÒWE 29
Orin 28 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Má Ṣe Lọ́wọ́ sí Àwọn Àṣà Tí Kò Bá Bíbélì Mu
(10 min.)
Wàá ní ayọ̀ tòótọ́ tó o bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà (Owe 29:18; wp16.6 6, àpótí)
Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n kó o lè mọ̀ bóyá àṣà kan bá Bíbélì mu (Owe 29:3a; w19.04 17 ¶13)
Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni mú kó o lọ́wọ́ sí àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu (Owe 29:25; w18.11 11 ¶12)
O ò ní lọ́wọ́ sí àṣà tí kò bá Bíbélì mu tó o bá ń ṣèwádìí látinú Bíbélì, tó o sì ń fi sùúrù ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 29:5—Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ará látọkàn wá? (w17.10 9 ¶11)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 29:1-18 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe ẹni náà wá sí àkànṣe àsọyé tá a máa gbọ́ láìpẹ́ (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi Ilé Ìṣọ́ No. 1 2025 wàásù fẹ́nì kan. Yí ọ̀rọ̀ ẹ pa dà nígbà tó o rí i pé ohun míì lẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)
6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(5 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fún ẹnì kan tó ń ṣàníyàn nípa bí ogun ṣe ń jà kárí ayé ní Ilé Ìṣọ́ No. 1 2025. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)
Orin 159
7. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(15 min.)
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ọ̀rọ̀ ìṣáájú apá 4 àti ẹ̀kọ́ 14-15