ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp23 No. 1 ojú ìwé 5
  • Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mó Bá Ń Ronú Àtipa Ara Mi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé Mo Lè Rí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Máa Tù Mí Nínú Nínú Bíbélì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Àárẹ̀ Ọpọlọ Máa Dohun Ìgbàgbé!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
  • Àárẹ̀ Ọpọlọ​—Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
wp23 No. 1 ojú ìwé 5
Ọ̀dọ́kùnrin kan jókòó sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì rẹ̀, ó ń ka Bíbélì.

Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Rẹ

INÚ Bíbélì la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dáa jù lọ torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn, ó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá wà nínú ìṣòro tó lágbára, tí èròkerò bá ń wá sí wa lọ́kàn, tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn, àárẹ̀ ara tàbí ti ọpọlọ.

Ohun kan tó fini lọ́kàn balẹ̀ jù lọ ni pé, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wa yé Jèhófà Ọlọ́runa Ẹlẹ́dàá wa, ó sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa ju ẹnikẹ́ni míì lọ. Ó máa ń wù ú gan-an láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn ẹsẹ Bíbélì méjì tó ń tuni nínú yìí:

“Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.”​—SÁÀMÙ 34:18.

“Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’” ​—ÀÌSÁYÀ 41:13.

Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní àárẹ̀ ọpọlọ tó ń fa ìdààmú ọkàn tàbí ìsoríkọ́? Bá a ṣe máa rí i nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níwájú, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Jèhófà ń gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́