Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
APRIL 2023
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ: JUNE 5–JULY 9, 2023
© 2023 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ìtẹ̀jáde yìí kì í ṣe títà. Ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tá à ń fi ọrẹ àtinúwá tì lẹ́yìn. Tó o bá fẹ́ ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ lọ sí ìkànnì donate.jw.org.
Inú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun la ti mú gbogbo ẹsẹ Bíbélì tá a lò, àfi tá a bá sọ pé Bíbélì míì la lò.
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ:
Ogún ọdún (20) ni Jékọ́bù fi ṣiṣẹ́ kára fún Lábánì ẹ̀gbọ́n ìyá ẹ̀, síbẹ̀ ó rẹ́ ẹ jẹ. Àmọ́ Jèhófà bù kún Jékọ́bù (Wo àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 17, ìpínrọ̀ 5)