ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 78-81
  • Sierra Leone àti Guinea

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sierra Leone àti Guinea
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 78-81
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 78, 79]

Sierra Leone àti Guinea

NÍ NǸKAN bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ọdún sẹ́yìn, igi àràbà kan fìdí múlẹ̀, ó sì ta gbòǹgbò sí ẹ̀bá Odò Sierra Leone. Fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún tí igi yìí fi ń dàgbà, iṣẹ́ ibi kan ń wáyé ní sàkáání ibi tí igi náà wà. Àwọn ọ̀dájú èèyàn tó ń ṣe òwò ẹrú ń kó nǹkan bí ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000] èèyàn kọjá lọ́kùnrin àti lóbìnrin títí kan àwọn ọmọdé, wọ́n ń kó wọn lọ tà sí oko ẹrú lókè òkun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 81]

Igi Àràbà tó jẹ́ mánigbàgbé ní ìlú Freetown

Ní March 11, 1792, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ẹrú tó dòmìnira láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà kóra jọ sí abẹ́ Igi Àràbà yìí láti ṣàjọyọ̀ ìpadàbọ̀ wọn sí ilẹ̀ Áfíríkà. Lọ́jọ́ yẹn, wọ́n tẹ ìlú kan dó nítorí ayọ̀ tí wọ́n ní pé ọwọ́ wọn tẹ ohun tí wọ́n ń retí, wọ́n sì pe orúkọ ìlú náà ní Freetown. Bí àwọn ẹrú tó dòmìnira tó ń dé sí ìlú Freetown ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, iye ẹ̀yà ilẹ̀ Áfíríkà tó wà ní ìlú náà wá lé ní ọgọ́rùn-ún [100]. Gbogbo ìgbà tí àwọn tó dé láti ìgbèkùn yìí bá ń rí Igi Àràbà náà ló máa ń rán wọn létí òmìnira àti ìrètí tí wọ́n ní.

Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone ti ń tu àwọn aládùúgbò wọn nínú pé òmìnira míì tó tún ṣàrà ọ̀tọ̀ ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Òmìnira yìí máa jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run tí Mèsáyà ń ṣàkóso bá mú àlàáfíà wá tó sì tún sọ ayé di Párádísè.—Aísá. 9:6, 7; 11:6-9.

Ó ti lé ní àádọ́ta [50] ọdún báyìí tí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone ti ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè Guinea. Orílẹ̀-èdè Guinea tó pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Sierra Leone yìí ti ní ọ̀pọ̀ ìṣòro, irú bíi rògbòdìyàn òṣèlú, ipò ọrọ̀ ajé tí kò rọgbọ àti oríṣiríṣi rúkèrúdò táwọn èèyàn dá sílẹ̀, èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ ará ìlú náà fetí sí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ látinú Bíbélì.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone àti Guinea ń wàásù ìhìn rere kódà láwọn ìgbà tí nǹkan ò rọgbọ. Lára àwọn ìṣòro tí wọ́n ní ni gbígbọ́ bùkátà, ipò òṣì paraku, àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó ti mọ́ àwọn èèyàn lára, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìwà ipá tó burú jáì. Ìtàn inú ìwé yìí jẹ́rìí sí i pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yìí jẹ́ olóòótọ́, wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, wọ́n sì ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn. A nírètí pé ìtàn wọn máa wọ̀ ẹ́ lọ́kàn, á sì mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú “Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìrètí” túbọ̀ lágbára sí i.—Róòmù 15:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́