SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
Gbogbo Wọn Ló Fẹ́ Wò Ó
LỌ́DÚN 1956, àwọn ará ní ìlú Freetown fi fíìmù The New World Society in Action han àwọn èèyàn. Wọ́n ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ pé:
“A gba gbọ̀ngàn tó tóbi jù ní ìlú Freetown, a sì pín ẹgbẹ̀rún [1,000] ìwé ìkésíni. A ò kúkú mọ iye èèyàn tó máa wá. Àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] péré ló wà níkàlẹ̀ nígbà tó ku ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kí fíìmù náà bẹ̀rẹ̀. Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lẹ́yìn náà, ọgọ́rùn-ún [100] èèyàn dé. Kò pẹ́ rárá tí ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ìjókòó tó wà ní gbọ̀ngàn náà fi kún. Síbẹ̀, tayọ̀tayọ̀ ni àwọn ọgọ́rùn-ún [100] míì fi gbà pé àwọn máa wà ní ìdúró. Àwọn ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] míì sì wà níta tí wọn ò ráyè wọlé. A bi wọ́n pé ṣé wọ́n máa wo fíìmù náà lẹ́yìn tí a bá parí ti àkọ́kọ́? Wọ́n dáhùn pé ‘Bẹ́ẹ̀ ni!’ Wọ́n sì dúró lóòótọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé òjò ń rọ̀.”
Látìgbà yẹn wá, ó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin [80,000] èèyàn káàkiri orílẹ̀-èdè Sierra Leone tó wá wo fíìmù yìí àtàwọn fíìmù wa míì tó lárinrin.