SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
Báàjì Àyà Ló Jẹ́ Kí Wọ́n Lè Kọjá
“LỌ́DÚN 1987, ó lé ní ẹgbẹ̀rún [1,000] èèyàn tó wá sí Àpéjọ Àgbègbè ‘Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Jèhófà’ tí a ṣe ní ìlú Guékédou, lórílẹ̀-èdè Guinea. Torí pé ibi tá a ti ṣe àpéjọ náà kò jìnnà sí ààlà Sierra Leone àti Làìbéríà, ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá sí àpéjọ náà láti àwọn orílẹ̀-èdè yìí ló ń wá láti ilé wọn. Àmọ́ wọn ò ní àwọn ìwé àṣẹ ìrìnnà. Torí náà, àwọn arákùnrin tó ń bójú tó ìrìn àjò náà bá àwọn ọ̀gà aṣọ́bodè ṣe àdéhùn. Ohun kan ṣoṣo tí àwọn tó máa wá sí àpéjọ náà nílò ni báàjì àpéjọ àgbègbè wọn! Tí àwọn ọlọ́pàá aṣọ́bodè bá ti rí báàjì àyà wọn, ṣe ni wọ́n á juwọ́ sí wọn pé kí wọ́n kọjá.”—Arákùnrin Everett Berry tó jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀.
Àwọn ará gbádùn oúnjẹ ní àpéjọ àgbègbè yìí