Svaneti Òkè
JỌ́JÍÀ
Àlàyé Ṣókí Nípa Jọ́jíà
Ìkórè èso àjàrà máa ń múnú wọn dùn
Ilẹ̀ Àwọn èèyàn mọ orílẹ̀-èdè Jọ́jíà dáadáa torí àwọn òkè ńláńlá tó wà níbẹ̀ àtàwọn òkè gíga tí yìnyín bò, àwọn òkè kan tiẹ̀ ga ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] ẹsẹ̀ bàtà lọ. Apá méjì ni wọ́n pín orílẹ̀-èdè Jọ́jíà sí, ìyẹn ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn. Apá kọ̀ọ̀kan ló ní oríṣiríṣi ilẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan ló sì ní ojú ọjọ́ tó yàtọ̀ síra, àṣà, orin, ijó àti oúnjẹ tirẹ̀.
Àwọn Èèyàn Ọmọ ìbílẹ̀ Jọ́jíà ni èyí tó pọ̀ jù nínú mílíọ̀nù mẹ́ta ó lé ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [3,700,000] èèyàn tó ń gbé ibẹ̀.
Ẹ̀sìn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní Jọ́jíà ń lọ. Ẹ̀sìn Mùsùlùmí sì ni ìdá kan nínú mẹ́wàá wọn ń ṣe.
Èdè Èdè Jọ́jíà yàtọ̀ pátápátá sí èdè táwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń sọ. Ìtàn fi hàn pé àwọn álífábẹ́ẹ̀tì inú èdè Jọ́jíà ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì ti wà ṣáájú àkókò tiwa yìí.
Iṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́ Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ibẹ̀ fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, báwọn èèyàn ṣe wá ń gbafẹ́, tí wọ́n sì ń wo àwọn ohun mèremère tó wà ní Jọ́jíà wà lára ohun pàtàkì tó ń mówó wọlé fún wọn lórílẹ̀-èdè náà.
Ojú Ọjọ́ Ojú ọjọ́ bára dé fáwọn tó ń gbé ní apá ìlà oòrùn Jọ́jíà. Ní apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà, ojú ọjọ́ máa ń gbóná fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ létí Òkun Dúdú, àwọn èso bí ọsàn àti àjàrà sì máa ń pọ̀ gan-an níbẹ̀.
Wọ́n ń kórè èso àjàrà ní àgbègbè Kakheti
Oúnjẹ Àwọn ará Jọ́jíà ò lè ṣe kí wọ́n máà ní búrẹ́dì lórí tábìlì wọn tí wọ́n bá fẹ́ jẹun. Inú ààrò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe ni wọ́n ti máa ń ṣe búrẹ́dì ìbílẹ̀. Ọbẹ̀ tó ki, tòun ti èròjà àti ewébẹ̀ gangan ni oúnjẹ wọn. Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe wáìnì ní Jọ́jíà. Tí wọ́n bá ti ṣe wáìnì tán, inú àwọn ìkòkò amọ̀ ńlá ni wọ́n máa ń tọ́jú ẹ̀ sí. Ọ̀pọ̀ ìdílé ló máa ń gbin èso àjàrà tiwọn, tí wọ́n sì máa ń ṣe wáìnì fúnra wọn. Oríṣi èso àjàrà tó tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ló wà lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà.
Bí wọ́n ṣe ń ṣe búrẹ́dì ìbílẹ̀