ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 90
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àìsàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àìsàn
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Nǹkan Ṣì Lè Pa Dà sí Bó Ṣe Wà Tẹ́lẹ̀ Ṣáájú Àrùn Corona? Bí Bíbélì Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Àrùn Corona Má Bàa Jẹ́ Kí Nǹkan Tojú Sú Ẹ
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àrùn Kòrónà Ti Pa Mílíọ̀nù Mẹ́fà Èèyàn—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àárẹ̀ Ọpọlọ​—Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 90
Ìyá kan gbé ọmọ ẹ̀ tó ń sunkún dání, ó ń dúró de àwọn dókítà.

John Moore/Getty Images

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àìsàn

“Torí pé àrùn Kòrónà kì í ṣe ọ̀rọ̀ pàjáwìrì mọ́ kárí ayé kò túmọ̀ sí pé àrùn yìí ti kásẹ̀ nílẹ̀.. . . Àfi ká múra sílẹ̀ báyìí torí ó dájú pé àjàkálẹ̀ àrùn míì ṣì máa jà.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n Tedros Adhanom Ghebreyesus, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà Àjọ Ìlera Àgbáyé, May 22, 2023.

Ràbọ̀ràbọ̀ àrùn Kòrónà ṣì ń fa ìdààmú ọkàn fún ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tó jẹ́ pé àwọn míì ṣì ń jìyà ẹ̀ títí dòní. Ṣé àwọn ìjọba àtàwọn elétò ìlera lè yanjú ìṣòro àìsàn tó ń bá aráyé fínra lásìkò yìí, ká má tíì sọ pé kí wọ́n múra sílẹ̀ de àjàkálẹ̀ àrùn míì tó máa jà lọ́jọ́ iwájú?

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba kan tó máa jẹ́ ká ní ìlera tó dáa. Ó ní: “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀.” (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ ìjọba náà, ‘kò ní sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.” ’ (Àìsáyà 33:24) Gbogbo èèyàn ló máa ní ìlera tó dáa, wọ́n sì máa lágbára bí ìgbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́.—Jóòbù 33:25.

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

“Ilé Ìṣọ́” tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?”

A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka Ilé Ìṣọ́ tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?” Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi:

  • Ta Ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run?

  • Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?

  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́