ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwfq àpilẹ̀kọ 63
  • Ṣé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tako Gbígba Abẹ́rẹ́ Àjẹsára?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tako Gbígba Abẹ́rẹ́ Àjẹsára?
  • Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Gba Ìtọ́jú Lọ́dọ̀ Àwọn Dókítà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Bó O Ṣe Lè Mọyì Ìwàláàyè Tí Ọlọ́run Fún Ẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí fún Ìtọ́jú Pàjáwìrì
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àìsàn Bá Dé Láìròtẹ́lẹ̀
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwfq àpilẹ̀kọ 63
Lára ohun tí wọ́n fi ń fúnni ní abẹ́rẹ́ àjẹsára ni abẹ́rẹ́ àtàwọn ìgò kéékèèké tí oògùn wà nínú ẹ̀.

Ṣé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tako Gbígba Abẹ́rẹ́ Àjẹsára?

Rárá. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tako gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára. A gbà pé Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá kóun gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tàbí kóun má ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti pinnu láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára.

Tá a bá ń ṣàìsàn, a máa ń wá ibi tí wọ́n ti lè tọ́jú wa lọ́nà tó dáa. Inú wa sì ń dùn sí ìtẹ̀síwájú tó ń bá ìmọ̀ ìṣègùn. A tún mọyì àwọn dókítà àtàwọn elétò ìlera nítorí iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe, pàápàá nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ìlera. Bí àpẹẹrẹ, látìgbà tí àrùn Corona ti bẹ̀rẹ̀ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń gbé onírúurú ìsọfúnni jáde ní ọ̀pọ̀ èdè sórí ìkànnì yìí, a sì ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ìjọba gbé kalẹ̀ lórí bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa. Lára àwọn ìtọ́ni tí wọ́n fún wa ni pé, ká máa jìnnà síra, ká má kọjá iye tí wọ́n sọ pé ó lè péjọ síbì kan, ká máa ya ara wa sọ́tọ̀ tá a bá rí i pé a ní àrùn, ká máa fọ ọwọ́ wa, ká máa wọ ìbòmú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.—Róòmù 13:1, 2.

Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ìtẹ̀jáde awa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tẹnu mọ́ àwọn ìlànà yìí:

  • Kálukú ló máa pinnu ohun tó máa ṣe tó bá kan ọ̀rọ̀ ìlera.—Gálátíà 6:5.

    “[Ìwé Ìròyìn yìí] kò dámọ̀ràn àpẹẹrẹ-irú ìṣègùn tabi ìtọ́jú-ìwòsàn-ìṣègùn kan lékè òmíràn bẹẹni kò sì nawọ́ ìṣíníyè oniṣègun síni. Ìfojúsùn rẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ lati mú awọn òtítọ́-ìṣẹ̀lẹ̀ jáde kí a sì fi í silẹ fún òǹkàwé náà lati gbé awọn nńkan yẹ̀wò kí ó sì ṣe ìpinnu ara rẹ̀.”—Jí!, February 8, 1987.

    “Ìwọ lo máa pinnu bóyá ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ máa gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tàbí ẹ ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.”—Jí!, August 22, 1965.

  • A ma ń wá ìtọ́jú tó dáa torí pé ẹ̀mí ṣe pàtàkì sí wa.—Ìṣe 17:28.

    “Awọn Ẹlẹri Jehofah nṣe itọju ara wọn nipasẹ oriṣiriṣi ọgbọn iṣegun ti o le ran wọn lọwọ ninu iṣoro ilera wọn. Nwọn fẹran ìyè bẹni nwọn si nfẹ lati ṣe ohunkohun ti o ba le ṣeṣe ti o ba ọgbọn mu ti o si ba Iwe Mimọ mu pẹlu lati mu iwalaye wọn gun.”—Ilé Ìṣọ́, July 1, 1975.

    “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gba ìtọ́jú àti oògùn nílé ìwòsàn. Wọ́n fẹ́ kí ara wọ́n le, wọ́n sì ń fẹ́ kí ẹ̀mí àwọn gùn. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Kristẹni kan wà tó ń jẹ́ Lúùkù, dókítà ni, bákan náà lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà tí wọ́n jẹ́ dókítà. . . . Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì iṣẹ́ bàǹtàbanta táwọn dókítà ń ṣe láti tọ́jú àwọn èèyàn. Wọ́n sì tún ń fi ìmoore hàn fún bí wọ́n ṣe ń mú ìtura bá àwọn aláìsàn.”—Ilé Ìṣọ́, February 1, 2011.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́